Ọjọ l’ọjọ ti Imisioluwa Ayanwale ti ọpọ mọ si Imisi BB9JA gbe igba oroke ninu idije BB9JA ti ọdun 2025 lẹyin oṣu diẹ ti wọn lo ninu ile ẹlẹgbọn agba ta mọ si Big Brother Nigeria abi BB9JA. Ṣebi bi ere bi ere ni kini ọun bẹrẹ ninu idije BB9JA ti ọdun 2025, titi ti wọn fi kede orukọ Imisi gẹgẹ bii olubori ti ibo rẹ tẹ iwọn ju ninu idije naa.
Fẹ kan tẹlẹ, kii ṣe iroyin pe ọrọ ẹni ba wọ ile ẹlẹgbọn agba (BB9JA house) ti di guguru l’ẹnu ọpọ ara ilu. Lati ibẹrẹ pẹpẹ idije naa si ni aye ti n f’oju si ọmọbinrin Imisi yii lara t’ori ihuwasi rẹ to da yatọ gedengbe si t’awọn to ku, eyi si fa ki ọpọ awọn onworan eto naa fẹran rẹ ni t’ori igbadun ti ọrọ rẹ jẹ fun wọn. A mọ ṣa titi di asiko yii, oju ko kuro ni ara Imisi bẹẹ ni ẹnu ko sin ni ara rẹ.
Yatọ fun ẹbun owo tuulu aadọjọ miliọnu naira (₦150m) ati awọn ẹbun ohun mere-mere miran to to ni ariwo lọtọ, awuyewuye tun bẹ lori iru ile ti ọmọ yii ti ja’de wa. Wọn ni aarin Imisi ati iya rẹ ko gun rara nitori iya naa ko naani rẹ tẹlẹ ko di ogo to da lasiko yii. A mọ ṣa, iya Imisi iyẹn arabinrin Rashidat Ayanwale gan-an fun’ra rẹ ti bọ si’ta. N ṣe ni iya naa ṣe fọnran to gbe ja’de lori ikanni TikTok.
Ninu fọnran ni iya Imisi ti kọkọ dupẹ pataki l’ọwọ awọn to fi ifẹ han si ọmọ oun lati ja’we olubori pe wọn ṣeun. Iya yii ko duro si’bẹ, n ṣe lo tun kilọ fun awọn to’n pe oun kii ṣe iya gidi si Imisi, pe oun lee danu lati kekere pe ki wọn o ṣọ ẹnu gidigidi t’ori ewu dida si ọrọ aimọdi.
Pabambari to ti wa da họhu-họhu si’lẹ ni pe iya yii fẹ ki Imisi o fi ọla mọ oun nitori oun ko ri oju Imisi nilẹ rara, to si jẹ pe oun naa gbiyanju ohun ti ipa ka lati jẹ ki ọmọ naa ṣe aṣeyọri.
Amọ ṣa, n ṣe ni ọrọ n ru awọn ninu pe iru alusi iya wo ree to jẹ pe ko bikita abi ji’ya l’ori ọmọ ṣugbọn to n fẹ lati jẹ ere jẹ ọrọ ọmọ, awọn wọn yii n pe apẹrẹ iwa ailojutu ni fọnran yii jẹ fun iya naa nitori ti o fẹ da ebiti aya kọ ọbẹ ti ko mọ bo ṣe jina.
Bẹẹ awọn miran l’ori ayelujara yii kanaa n pe, iya ni a iya a maa jẹ labẹ bo ti wu kori, pe ki Imisi o tete ṣe atunṣe, ko si fa iya rẹ mọ’ra.