Ẹ JA’WỌ L’ỌRỌ EMI ATI IYAWO MI – 2BABA P’AWORI F’ỌMỌ NAIJIRIA

L’aarin awuyewuye nla to gb’ode kan l’ori ọrọ eekan olorin nni, Innocent Ujah Idibiah ti ọpọ mọ si 2Baba abi 2Face ati aya rẹ tuntun ti tun ṣe aṣofin ni ipinlẹ Edo, Natasha Osawaru ni 2Face fun’ra rẹ ti ke gbajari si’ta ni’bi to ti n bẹ awọn ọmọ Naija lati jẹ ki ogun o mi, ki wọn o m’ẹnu kuro l’ọrọ oun ati iyawo rẹ.


2Baba sọ ninu fọnran kan to ju si’ta lati fi da awọn eniyan, to fi mọ awọn gbajumọ, to ti dasi ọrọ naa l’ẹkun riru’gbo si wahala to n ṣẹlẹ. Bẹẹ si re, ile aṣofin Edo naa ti ranṣẹ pe Natasha l’ori ọrọ yii.

Wọnyi ni awọn ọrọ ti 2Baba sọ ninu fọnran naa:
“Ọrọ yi ti n ba ọwọ bọ s’ori, ti eyi si l’ewu jọjọ. Mo mọ oun ti awọn olulufẹ ati awọn eniyan lee ṣe. Ninu alaafia pipe ni mo wa. Ṣe o n ye? Ọrọ yi ti n ko Natasha si’nu ewu. Iru eyi ko tọ si ẹnikẹni. Mo fẹ kiki kaluku o sinmi agbaja ati ọtẹ. Gbogbo ọrọ la o yanju pata. Ko le ṣe ki asọ o ma wa, eyi kọ ni akọkọ. Ọrẹ, mọlẹbi, ẹni gbogbo ko da’wọ ogun duro. Mo bẹ yin ni. Alaafia ni mo wa, mi o dẹ k’igbe fun iranwọ. Ẹ jọwọ, ayọ ni mo wa, ẹ dakun (ẹ dẹkun ọtẹ).”

Ẹwẹ, ẹ ranti pe lati igba ti ina ọrọ naa ti jo f’aye ri ni kaluku ti n m’ẹnu le, ninu rẹ la si ti ri awọn gbajumọ bi Tẹni Makani olorin, Nasboi ati Saidaboj laarin awọn miiran. Tẹni f’ọrọ naa da apara pe o ti di dandan f’awọn lati wa doola agba-ọjẹ olorin naa silẹ ninu igbeyawo “hahamọ” to wa, bẹẹ ni Saidaboj ni tiẹ ni 2Baba gan-an ni iṣoro t’ori pe o pade obiririn ti ko gba igbakugba bi awọn obinrin to ku ti 2Face ti fẹ lo jẹ ki ariwo, o pe 2Baba gan-an fun’ra rẹ ni ko yẹ ara rẹ wo. Nasboi ni tiẹ ni inu oun ko dun si gbogbo iṣẹlẹ yii t’ori irufẹ ohun bayii kọ ni oun fi mọ 2Face ti oun ti mu ni alawokọṣe (model) lati ọmọ ọdun mẹrindilogun (16). O rọ 2Face lati tete ṣe atunṣe.

Titi di asiko yii, ina ọrọ naa ṣi n jo geerege, ti awọn kan si n pe 2Face pada ko oni tiẹ l’ẹyin to ja iyawo rẹ tẹlẹ, Annie Macaulay ju si’lẹ. Bẹẹ ni awọn kan n pe 2Face nilo iranlọwọ gidigidi l’asiko yii lati bọ kuro ninu “ọfin” to jin si.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search