Eyi Ni Bi Ọrọ Owo Ṣe Di’ja L’aarin Davido ati VDM

Eyi Ni Bi Ọrọ Owo Ṣe Di'ja L'aarin Davido ati VDM

Ejijangbara lori ayelujara, Vincent Otse ti gbogbo eeyan mọ si VDM lo ti ṣalaye idi ti oun ati Davido o ṣe jọ ṣe mọ.

VDM ninu fọnran kan to n tan ka bayi lo ni Davido dẹkun ati maa ba oun sọrọ lẹyin t’oun kọ aadọta miliọnu lati polongo fun aburo Baba rẹ to jẹ Gomina ipinlẹ Ọsun, Ademola Adeleke.

O sọ ọrọ yii lẹyin awuyewuye oriṣiriṣi nipa ohun to ṣokunfa aawọ wọn. O ni bi wọn ṣe pe oun lati wa pade gomina k’oun le gba owo naa l’oun kọ jalẹ pẹlu pe ọpọlọpọ owo ni.

O tẹsiwaju pe nkan ti ọpọ eeyan o ba mọ lori ayelujara maa n ṣ’agba wọn. VDM ni igba ti oun ati Davido sọrọ kẹyin ni igba ti Davido ṣeleri lati fun ọmọ kan lowo ni Ghana ṣugbọn o da bi pe o gbagbe. O ni lẹyin yẹn oun fi atẹjiṣẹ ranṣẹ si, wọn dẹ san owo naa.

 

Ọrọ ti VDM sọ yii lo ti wa fa ariwisi oriṣiriṣi lori ayelujara nipa ibaṣepọ aarin awọn gbajugbaja ati oṣelu l’orilẹ-ede Naijiria.

VDM lo pade Davido ni ọdun 2023 ti awọn mejeeji si jọ n ba ọrẹ wọn bọ diẹ-diẹ. Ọdun 2025 ni awọn eeyan kọkọ bẹrẹ awuyewuye lori pe awọn mejeeji ti yapa lẹyin ti VDM bu ẹnu atẹ lu Davido, Wizkid ati Burna Boy pe wọn n na inakuna. Lẹyin eyi ni VDM sọ awọn oko ọrọ diẹ diẹ si Davido to si pe ni awun.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search