CHEF DAMMY ỌJỌSI TI PADA DI AKỌSẸMỌṢẸ ỌLỌWOṢIBI

Ọmọbinrin ọlọwọ ṣibi kan ti orukọ rẹ n jẹ Damilọla Adeparusi ti ọpọ mọ si Cheff Dammy ti okiki rẹ kan ni ọdun 2023 nitori to gbiyanju ati fi iyun le’lẹ fun ami ẹyẹ Guiness World Records gẹgẹ bii alase to da’na fun igba pipẹ julọ l’agbaye ṣugbọn ti igbiyanju naa ko lọ daadaa to.
 Ti eyi si mu ki awọn eniyan  ma da yẹyẹ rẹ lawujọ paapaa julọ pẹlu bi agba ọjẹ alase miran iyẹn Hilda Bacci ti ṣe ṣẹṣẹ pa iru itu bẹẹ tan l’asiko igba naa.

L’ọwọ yii, Chef Dammy tun wọ iroyin pada pẹlu bi ko ṣe lee pa idunnu rẹ mọ’ra ninu atẹsọwọ (post) kan to gbe ja’de l’ori ikanni Instagram rẹ eyi to ni aworan Chef Dammy ninu ile idana ile-ẹkọ akọsẹmọṣẹ alase kan to gbajumọ nilu Eko ni’bi ti Chef Dammy ti ṣẹṣẹ k’ẹkọọ yege gẹgẹ bii ojulowo akọsẹmọṣẹ alase.

Bakanna ni Dammy tun dupẹ pataki l’ọwọ gbogbo awọn ejika ti ko jẹ ki aṣọ o yẹ l’ọrun rẹ pe wọn ṣe wọn ku aduroti. Ti ko si ru’ju pe lootọ ni ọdọmọbinrin alase yii ri aanu gba koda to fi de ọdọ ijọba ipinlẹ Ekiti ti Dammy funra rẹ ti wa. Bẹẹ lo su’re ibukun fun gbogbo awọn onigbọwọ ati awọn aladuroti rẹ, to fi mọ orilẹ-ede Naijiria ati ara rẹ.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search