Ile-ẹjọ wọgi le ẹbẹ Wasiu Ayinde lori ọrọ Awujalẹ tuntun, amọ…

Latari bo ṣe wọ Gomina atawọn afọbajẹ re kootu, eyi laṣẹ ti Adajọ pa fun KWAM 1 lori ọrọ ipo Awujalẹ Ijẹbu

Awuyewuye lori ọrọ yiyan ẹni ti yoo gori apere gẹgẹ bii Awujalẹ ti ilẹ Ijẹbu tuntun, eyi to ti n ja ranyin lati ọsẹ diẹ sẹyin, pẹlu bi gbajugbaja onkọrin Fuji to tun jẹ Olori Ọmọọba ilẹ Ijẹbu, Wasiu Ayinde Ọlasunkanmi Ọmọgbọlahan Marshall, ti gbogbo aye mọ si KWAM 1 tabi K1 de Ultimate, ṣe taku pe oun gbọdọ de ipo awọn babanla oun ọhun, ti gba ọna mi-in yọ bayii, ile-ẹjọ giga kan nipinlẹ Ogun, ti wọgi le ẹbẹ pataki kan ti ọkunrin naa bẹbẹ rẹ, pe ki wọn ba oun da ijọba ipinlẹ Ogun ati gbogbo awọn ti ọrọ iyansipo Ọba Awujalẹ kan lọwọ kọ na, pe ki wọn ṣi lọọ wa ibikan jokoo si na titi tile-ẹjọ yoo fi gbe idajọ kalẹ lori ẹtọ oun lati wa lara awọn ti yoo dupo Awujalẹ ọhun, ile-ẹjọ ti ni ẹbẹ ti ko mọyan lori ni Wasiu Ayinde gbe wa siwaju kootu yii, awọn ko si le pa iru aṣẹ radarada bẹẹ rara.

Ṣugbọn Adajọ Ọmọniyi ni nigba ti kootu yẹ gbogbo alaye ati awijare KWAM 1 wo, awọn ri i pe ẹsun ati ẹbẹ rẹ ko tẹwọn de ibi ti kootu yoo fi paṣẹ lati da awọn afọbajẹ lọwọ kọ, kaka bẹẹ, wọn ni niṣe ni ki Olori Ọmọọba ati gbogbo awọn to pe lẹjọ tete bẹbẹ si i gbaradi lati waa wi awijare ati atotonu wọn ni kootu, bẹrẹ lati Januari fọtin-in, ki ile-ẹjọ le pinnu ibi ti igi ẹjọ ti Ọmọgbọlahan pe yii yoo wo si jare.

Tẹẹ o ba gbagbe, lati ọjọ kẹtala, oṣu Keje, ọdun 2025 yii ni ipo Awujalẹ ti ilẹ Ijẹbu ti ṣi silẹ, latari bi Ọba Sikiru Kayọde Adetọna, ṣe tẹri gbaṣọ lẹni ọdun mọkanlelaaadọrun-un lẹyin aisan ra-n-pẹ kan.

Amọ ṣa o, ile-ẹjọ tun sọ pe ni ti ọrọ boya Wasiu Ayinde lẹtọọ lati wa lara awọn ọmọ-ọba ti yoo dupo Awujalẹ, wọn ni ko sohun to buru ninu ẹbẹ yii, ati pe bii ọrọ afọwọfọna ti wọn ni kii duro rojọ lawọn yoo fi igbẹjọ naa ṣe, wọn ni ni wara-n-ṣeṣa, bẹrẹ lati ọjọ kẹrinla oṣu Kinni, ọdun 2026, igbẹjọ gbọdọ bẹrẹ sii waye lori awọn ẹsun ti KWAM 1 tori rẹ pe ẹjọ, ilana kán-kàn-án-kán l’ole n wúre, eyi tawọn eleebo n pe ni accelerated hearing, lawọn yoo gbe ẹjọ naa gba, ki idajọ le tete waye lori rẹ laipẹ laijinna.

Onidaajọ A. A. Ọmọniyi, ti ile-ẹjọ giga ipinlẹ Ogun kan, eyi to fikalẹ siluu Ijẹbu Ode, nipinlẹ Ogun, lo paṣẹ naa lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kejilelogun, oṣu Kejila, ọdun 2025 yii, lori ẹjọ nla kan ti KWAM 1 pe Gomina ipinlẹ Ogun, Ọmọọba Dapọ Abiọdun, Olori ẹbi Fusẹngunwa n’Ijẹbu Ode, Ọtunba Lateef Owoyẹmi atawọn mi-in, ninu iwe ipẹjọ ti nọmba rẹ jẹ HC3/238/2025.

Ẹ o ranti pe lọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kejila, ọdun yii ni eekan olorin Fuji, to tun jẹ oye Mayegun ti ilẹ Yoruba yii pe ẹjọ siwaju ile-ẹjọ giga ọhun pẹlu ẹsun pe bo tilẹ jẹ pe idile Fidipọtẹ loun ti wa, oun ko ri idi ti awọn igbimọ to n boju to eto yiyan Awujalẹ tuntun yoo fi sọ pe idile Fusẹngbunwa nikan ṣoṣo lo gbọdọ fa awọn ọmọ-oye kalẹ lasiko yii, tori ko si bi ọbọ ṣe ṣe ori ti inaki ko ṣe, gbogbo ẹni to ba jẹ ọmọọba lo lẹtọọ lati jade dupo, lai fi ti ila idile ọba ti onitọhun ti wa pè.

Tori eyi, Oluaye Fuji ni kile-ẹjọ ba oun da awọn ti wọn n ṣeto yiyan Awujalẹ tuntun yii duro na, o ni kile-ẹjọ da wọn lọwọ kọ foun, nitori igbimọ afọbajẹ naa ti ṣẹ lodi si ofin ọba jijẹ nipinlẹ Ogun, eyi to faaye gba oun lati wa lara awọn ti yoo dupo, lai fi ti idile Fidipọtẹ toun ti jade wa ṣe.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search