Gomina tẹlẹri nipinlẹ Rivers to tun jẹ adije dupo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu ADC, Rotimi Amaechi ti kọ esi abajade idibo abẹle ẹgbẹ naa to si n ṣapejuwe wọn gẹgẹ bii eru.
Amaechi to jẹ ọkan lara awọn tiwọn jade gba fọọmu iferongba han lati dije dupo aarẹ pẹlu igbakeji aare tẹlẹri Atiku Abubakar ati onimọ nipa ọrọ aje Mohammed Hayatu-Deen lo fi aidunnu rẹ han lori itakun ibanidọrẹ X rẹ.
Ẹni to ti figba kan jẹ minisita fun igbokegbodo ọkọ nilẹ yii lo sọ pe ọpọ awọn ọmọ ẹgbẹ ni wọn o raye dibo kaakiri awọn ipinlẹ ati olu-ilu wa.
O tẹsiwaju pe lootọ l’oun ti sọ tẹlẹ pe oun maa gba esi idibo naa to ba yaranti lai ni bayobayo ninu ṣugbọn oun o le gba esi yii nitori ko fi ohun ti ẹgbẹ naa duro fun han leyi to yẹ ko yọ awọn ọmọ orilẹede Naijiria kuro ninu hila-hilo ti ijọba to wa l’ode n foju wọn ri.
O fikun pe ida ọgọrin awọn ọmọ ẹgbẹ ni wọn o fun laye lati dibo nitori naa ko ṣeeṣe ki oun gba esi yẹn.
Amaechi ni dida ti awọn da ẹgbẹ naa silẹ ni lati fun awọn ọmọ orilẹede Naijiria ni iṣelu to yatọ si tijọba to wa l’ode.
Kikọ ti Amaechi kọ esi yii tẹle ti adije dupo ẹgbẹ ẹ Hayatu-Deen to kọ lati de’bi kika ati akojọ ibo naa nitori awọn aiṣedede to jẹyọ nibi idibo abẹle naa.
Gẹgẹ bii awọn esi ṣe n fi hàn Atiku Abubakar lo lewaju esi idibo abẹle naa.