Ogbontarigi irawọ oṣere ati agbe sinima ja’de, Kunle Afọlayan lo ti ja’de wa s’ọrọ nipa ere rẹ tuntun “Anikulapo 2: The Ghoul Awakens” ti wọn ṣe afihan l’ori ikanni Netflix yika nnkan ọgọrun orilẹ-ede. Gbajumọ adari ere yii lo kọja lọ s’oju-opo rẹ l’ori ikanni Instagram lati gbe fọnran kan ja’de pe oun ri oniruuru ariwisi (commentary) ati iyanana (review) ti oriṣiriṣi awọn eniyan ni nipa iṣẹ oun tuntun paapaa julọ awọn ti wọn pe Kunle ko ri ere t’ọtẹ yii ṣe.
Ninu esi rẹ ninu fọnran naa ni Kunle ti kọkọ dupẹ l’ọwọ awọn to ti wo ere naa, l’ẹyin naa lo wa f’esi pe “Mo ti ri oriṣiriṣi ariwisi nipa fiimu mi tuntun Anikulapo apa keji. Ati ẹni ti iṣẹ ere ye ati ẹni ti ko l’oye rẹ lo ti n fi ero wọn le’de. Mo ran ti nigba ti mo kọkọ ṣe sinima “Irapada” l’ọdun diẹ s’ẹyin, awọn kọọkan bu ẹnu atẹ lu ṣugbọn ti iṣẹ naa pada gba oniruuru ami-ẹyẹ ati oriyin. Bẹẹ naa ni fiimu “Figurine” ri l’asiko tiẹ.”
Kunle wa sọ siwaju si pe ko ya oun l’ẹnu pe awọn kan to tẹ’wọ gba iṣẹ naa daadaa, bẹẹ ni oun ko ni iru ireti bẹẹ naa tẹlẹ nitori “awọn onilakaye ẹda ni awọn ere ti wa wa fun, kii ṣe gbas-gbos. A ti ri awọn ọjọgbọn, awọn onimimọ to ti gbe oṣuba fun wa l’ori iṣẹ yii. Ere alabala pupọ (series) ni Anikulapo yii ti ko dẹ ti pari si ibi to de. Mo l’ero pe oye a tunbọ ma ye si.”
Pariari, Olootu sinima “Anikulapo” ni oun ko ni dẹkun lati ma ṣe oun to tọ nipasẹ ṣiṣe awọn ere onilaakaye to si ṣe “sadankata” f’awọn ti oye wọn o ba to nnkan l’ori awọn sinima oun.