Gbajugbaja arẹwa oṣere nni, Julianah Ọlayọde ti ọpọ mọ si Tọyọ Baby lati inu sinima olokiki kan – Jennifer’s Diary lat’ọwọ Funkẹ Akindele lo ti bọ si’ta ṣalaye ni’pa oriṣiriṣi gbọ’yi-sọ’yi to n lọ ni’gboro ni’pa Toyọ Baby.
Ninu fọnran kan ti oṣere naa ṣe to gbe ja’de l’ori ikanni Instagram l’ẹnu l’ọwọ l’ọwọ yii lo ti jẹ ko di mimọ pe gbọ’yi-sọ’yi pọ ni’pa oun pe onigberaga ati adaratan ẹda ni oun jẹ nitori pe oun kii ko ipa to ba ti ni ifẹnukonu ninu, ninu ere, ti eyi ti mu ki awọn agbesinima ja’de kọọkan ti inu wọn ko dun si ta kete si oun. .
Julianah wa sọ di mimọ pe oun ko ti yii ọkan oun pada l’ori kikọ ifẹnukonu ninu ere abi ṣiṣe ere onihoho ṣugbọn o n fẹ ki wọn o tẹ’wọ gba ipinu rẹ lai f’oju adaratan abi agbẹsin-l’ori wo oun, bẹẹ lo pe oun ko kọ lati ko awọn ipa miran to yatọ fun eyi, koda bo jẹ awọn ipa keekeekee.
Siwaju, irawọ oṣere yii wa bẹrẹ si ni ke si awọn gbajugbaja agbe sinima ja’de bii Biọdun Stephen, Mo Abudu, Jade Ọṣibẹru, Kayọde Kasum, Kẹmi Adetiba, CaptainDegzy, FilmBoyTheFirst lati ma pe oun si iṣẹ. Ẹwẹ, ninu abala awile (comment section) ni ọkan ninu awọn to darukọ FilmBoyTheFirst ti fọ esi pe awọn ti jọ ṣe iṣẹ ri, ti iṣẹ si tun wa ni iwaju. Ọgọrọ awọn ololufẹ to wa fọ esi fun lo n fi ifẹ han si, ti wọn si gba ni iyanju lati ma k’aarẹ ọkan rara, pe ọjọ ọla rẹ a dara.