MI O TETE MỌ PE ARARA NI MI – NKUBI

Ọkunrin arara kan to jẹ gbajugbaja oṣere, alawada ati agbohunsafẹfẹ, Victor Udochukwu Nwaogu ti ọpọ mọ si Nkubi lo ti sọ ọrọ ni’pa igbesiaye rẹ gẹgẹ bi arara, ati bi ọmọ rẹ obinrin, Soromtochukwu naa ṣe jẹ arara pẹlu.

Awọn ọrọ yii ni Nkubi mẹnuba l’asiko ti oun ati aya rẹ, Vivian Joseph ti awọn miran mọ si Ofoegbu Vivian Nkeiruka jọ n ko’pa ni’bi eto ifọrọwanilenuwo kan l’ori ayelujara. Nkubi ṣalaye ninu ọrọ rẹ pe oun ko tete l’oye nipa irufẹ eniyan ti oun jẹ gẹgẹ bii arara botilẹjẹ pe oun mọ lati kekere pe oun yatọ l’aarin awọn akẹgbẹ oun ṣugbọn ti oun to tun mọ si ko ye oun.

Ninu alaye Nkubi, o jẹ ko di mimọ pe, l’asiko t’oun bẹrẹ si ni wa iṣẹ l’ẹyin to pari ile-ẹkọ girima ni oun bẹrẹ si ni l’oye ni’pa itumọ bi irisi oun ṣe da yatọ. O ni oju oun bẹrẹ si ni la si jijẹ arara nigba ti wọn bẹrẹ si ni pe oun ni awọn orukọ bii “baba kekere, danku ati arara.”

Ko tan si’bẹ, Nkubi ni ki awọn o to be ọmọ wọn iyẹn ni awọn ti gba kamu pẹlu aya oun pe ninu ki ọmọ naa kuru abi ko jẹ arara bi ti baba rẹ l’eyi to pada ri bẹẹ, amọ ṣa ti iya rẹ pe oye naa a ma gba ọgbẹ l’ọkan oun nigba miran, koda oun ti ri dokita kan ri to gba oun l’amọran l’ati fi aatọ ẹlomiran ti kii ṣe arara bi ọkọ rẹ lati fi bi’mọ ṣugbọn ti oun kọ ja’lẹ.

Obinrin naa wa pe ireti oun ni pe irisi ọmọ wọn obinrin naa lee ran l’ọwọ l’ati jẹ model iyẹn awọn ayankiri-se-faari ni abala awọn ẹni kukuru ti awọn yoo si fun ni gbogbo iranwọ to ba fẹ.Ọgọrọ awọn ololufẹ lo ti wa n ṣugbọn Nkubi ati mọlẹbi rẹ, ti wọn si tun fi ọrọ tutu bọ wọn.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search