Mo Le Foriji Obinrin To Ba Yan Ale, Nkan Ti Ifẹ Otitọ Kọ Wa Niyẹn – Stan Nze

Gbajugbaja oṣerekunrin nni, Stan Nze ti sọ pe oun le dariji obinrin to ba n yan ale nitori pe ifẹ otitọ lo ja ju, o si ni agbara lati di aarin l’ọkọ l’aya mu ti wọn ba fi idariji, aanu ati aini imọtaraẹni nikan.

Nibi ifọrọwanilẹnuwo kan ti wọn ti bi oṣere naa pe njẹ ifẹ nikan to lo ti sọ pe igbagbọ oun ni pe ifẹ nikan tito, to ba jẹ ifẹ ootọ ti kii ṣe itanjẹ. O tẹsiwaju pe oun o sọrọ nipa ifẹ to jẹ ifẹ oju lasan bi kii ṣe ifẹ ti Kristi ti o l’abawọn ti Kristi kọ nigba aye rẹ.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, ifẹ otitọ ni ifẹ to maa n dariji lai ro leemeji, to maa n laanu, to ko si ni imọtaraẹni nikan. O ni ọpọlọpọ awọn ibaṣepọ lo maa n fori ṣọpọn nitori awọn l’ọkọ l’aya naa o kii n dariji ara wọn bẹẹ ni wọn maa n nira wọn sinu kaka ki wọn sọ ohun to n dun wọn ki wọn le pari ohun to n fa gbọnmisi-omi-o-to laarin wọn.

Nigba ti wọn bi Stan boya o le foriji iyanjẹ laarin l’ọkọ l’aya, o ni bẹẹni ṣugbọn eeyan o gbọdọ ri idariji gẹgẹ bii aaye lati maa gbagbakugba. O tẹsiwaju pe bibeli gan sọ pe a o le jokoo ninu ẹṣẹ, ki oore-ọfẹ maa pọ si i nitori naa bi o tilẹ jẹ pe aforiji ṣe pataki kii ṣe oore-ọfẹ lati maa wuwa k’iwa.

Ni akotan, Stan ni bi o tilẹ jẹ pe ifẹ faaye idariji silẹ fun awọn ti wọn ba ṣe ṣugbọn ọgbọn ati kiko ara ẹni nijanu ṣe pataki lati ni igbe-aye alaafia gẹgẹ bi ọkọ ati iyawo.

Stan Nze lo jẹ ọkọ fun oṣerebinrin ẹgbẹ rẹ Blessing Obasi-Nze ti Ọlọrun si fi ọmọ ọkunrin ta wọn lọrẹ.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search