Ọkan pataki ninu awọn alakoso (minisita) ninu ijọba Aarẹ Bọla Tinubu, ti tun ṣe alakoso f’ọrọ ina-ọba l’orilẹ-ede Naijiria, Adebayọ Adelabu Pẹnkẹlẹmẹẹsi ni aye ti fun ni orukọ tuntun bayii latari bi ọrọ ina ṣe n lọ laarin ilu. Lẹnu lọwọlọwọ yii ni orukọ Adelabu tun pada si ẹnu ọpọ awọn ọmọ orilẹ-ede Naijiria l’ori ayelujara ati laarin igboro latari bi ina-ọba ṣe di awaari, ti okunkun si gba ọpọ agbegbe ni Naijiria laarin bi ooru ṣe mu jọjọ ti awọn eniyan ko si ri atẹgun gba to nnkan.
Awọn ti ara wọn ko gba iru iriri yii mọ lo da Adelabu sọ lorukọ tuntun. N ṣe ni wọn gbe fọto rẹ kaakiri ori ayelujara pẹlu akori “Kabiesi, Ọba Adebayọ Adelabu Pẹnkẹlẹmẹẹsi Akọkọ, Olokunrun Birumu-Birimu ti Ilẹ Okunkun.” Irufẹ fọto ati awile yii ti wa gba ori ayelujara kan lọwọ yii.
Siwaju si, awọn miran naa n kọminu l’ori ọrọ Adelabu pe o ṣeeṣe ko soro fun ọkunrin naa lati de ipo gomina ni ipinlẹ Ọyọ nitori ipinlẹ Ọyọ gan-an wa ninu awọn ibi ti ina ọba ti kuro ni ṣege-ṣege to si ti fẹ di awaari ni ọpọ agbegbe.
Ẹwẹ, ẹ ranti pe baba to bi ba Adelabu iyẹn Oloye Oloogbe Adegoke Adelabu to n naa jẹ gbajugbaja oloṣelu ni orilẹ-ede Naijiria nigba aye reẹ naa gba inagijẹ “Pẹnkẹlẹmẹẹsi” (peculiar mess) l’atari gẹẹsi alagbara kan to fọ nile aṣofin l’ori iṣẹlẹ kan ti ko tẹ lọrun. L’ọwọ yii ọmọ-ọmọ rẹ to n naa ya sidi oṣelu tun ti gba orukọ kun orukọ botilẹjẹ pe eyi ko ba idunnu ara ilu de.