Mi O To Lati Gba Peller Ati Jarvis Niyanju Lori Igbeyawo - Frank Edoho
Ilumọọka sọrọsọrọ lori ẹrọ amohunmaworan, Frank Edoho lo ti kọ lati gba awọn t’ọkọ t’aya agbefọnranjade l’ori ayelujara Peller ati Jarvis ti wọn ṣẹṣẹ ṣe igbeyawo niyanju. O ni kaka k’oun gba wọn niyanju, oun a ṣ’adura fun wọn.
O sọ eyi nibi igbeyawo alarinrin awọn mejeeji l’ana ode yii. Nigba ti wọn pe Edoho lati gba awọn l’ọkọ l’aya naa niyanju lo kọ jalẹ.
O sọ eyi nibi igbeyawo alarinrin awọn mejeeji l’ana ode yii. Nigba ti wọn pe Edoho lati gba awọn l’ọkọ l’aya naa niyanju lo kọ jalẹ.
O ni ko yẹ ko jẹ oun ti oun o mọ nkankan nipa igbeyawo l’oun maa gba wọn niyanju. O ni o pe oun lati ṣ’adura fun wọn dipo k’oun gba wọn niyanju.
Edoho wa gba l’adura pe ki awọn l’ọkọ l’aya naa gbe igbe-aye idunnu, ibukun ati alaafia.
Ọrọ rẹ yii lo ti fa ariwisi oriṣiriṣi lori ayelujara pẹlu ohun ti oju rẹ ti ri pẹlu igbeyawo. Laipẹ yii ni iroyin igbeyawo keji rẹ si arabinrin Sandra gba ori ayelujara kan lẹyin to tuka lori ẹsun yiyan ale.