Nitori Peller TikTok, Olori ati Awọn Oloye Ilu Benin Kan Iyọnu

Igbimọ b’ọba-ṣe’lu ilu Benin ni ipinlẹ Edo lo ti bẹrẹ igbesẹ ibawi bayii fun olori kan l’aafin nitori ti wọn fi aaye gba gbajugbaja irawọ ori ikanni TikTok nni, Habeeb Hamzat Adelaja ti ọpọ mọ si Peller ni aafin Ọba ilu Benin lai gba iyọnda to yẹ, eyi ti wọn ti juwe gẹgẹ bii iwa abuku to ko ẹrẹ ba ori-ade.

Atẹjade ọrọ kan lati akata Frank Irabor ti ṣe Akọwe igbimọ b’ọba-ṣe’lu naa lo ṣalaye pe l’ọjọ kẹta oṣu kẹta ọdun 2026 yii ni wọn fi iru aaye ti ko tọ naa gba Peller lati ya wọ aafin Ọba Ewuare keji lai gba iyọnda to yẹ.

Peller ati awọn eniyan rẹ ni igbimọ naa pe wọn da ariwo silẹ ni aafin, ti abẹwo aitọna wọn naa si tun tabuku itẹ Ọba Benin nitori ti wọn pe aafin Ọba naa ki ṣe ibi ti ẹnikẹni kan le ku giri wọ abi wa ma ka fọnran silẹ nitori ti ko ba aṣa, iṣe ati iṣẹdalẹ ilu Benin ti wọn fi n tukọ aafin naa.

Ninu iwadii ti igbimọ b’ọba-ṣe’lu naa ti ṣe ni wọn ti ri pe ajere ọrọ ṣi mọ oloye kan l’ori, l’eyi to mu ki wọn o rọ l’oye, ti oṣiṣẹ kan l’aafin naa si tun ti wa ni akolo ọlọpa l’ori ọrọ, ti olori kan l’aafin naa si tun ti ri akoba nipasẹ iṣẹlẹ yii.

Igbimọ naa ti wa pe Peller lati wa ka’wọ pọn’yin ro’jọ awijare niwaju wọn, bi bẹẹ kọ, awọn yoo gboju agan nilana ofin si Peller. Ẹwẹ, Peller lo n bẹ l’ori abẹwo to n ṣe l’ọwọ si oniruuru ipinlẹ kaakiri orilẹ-ede Naijiria, bẹẹ lo tun jẹ pe arabinrin kan naa ti wọn jọ tahun sira wọn ni ile itaja kan naa tun ti pe Peller l’ẹjọ.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search