Ẹ Ye Fi Ẹmi Awọn Ọmọde Tafala Nitori Oṣelu – Femi Branch

Ẹ Ye Fi Ẹmi Awọn Ọmọde Tafala Nitori Oṣelu - Femi Branch

Ilumọọka oṣerekunrin, Femi Branch ti rọ awọn oloṣelu orilẹ-ede Naijiria lati ye fi ẹmi awọn ọmọde ṣ’ere nitori oṣelu.

Ẹbẹ naa to fi lede ninu fọnran kan lori itakun ibanidọrẹ Instagram rẹ lo waye pẹlu bi awọn ẹlẹkẹru agbesunmọmi ṣe n ṣe ikọlu si awọn ile-iwe kaakiri orilẹ-ede Naijiria, ti wọn si n ji awọn ọmọ gbe.

 

Nigba to n f’esi si ọrọ ti gomina ipinlẹ Ọyọ, onimọ-ẹrọ Seyi Makinde sọ lẹyin idasilẹ awọn ọmọ ti wọn jigbe nijọba ibilẹ Oriire, oṣere naa f’ẹsun kan awọn oloṣelu wipe ni ṣe ni wọn n fi ọrọ ijinigbe ṣe ere oṣelu booba-o-pa-booba-o-bu-lẹsẹ, to si n rọ wọn lati fi awọn ọmọde silẹ ti wọn ba fẹ ṣe iṣe oṣelu wọn.

Femi Branch ni, oun o k’oju si ẹnikẹni ni pato, ṣugbọn oun n ra’wọ ẹbẹ si gbogbo eeyan lati ma fi awọn ọmọ ṣe oṣelu. O ni iya ti jẹ awọn ọmọde to l’orilẹ-ede yii.

O fi kun pe, ile-iwe ti ọpọ wọn n lọ naa ko dantọ nitori gbogbo rẹ ti doju ru. Oṣere naa ni, ọjọ mẹrindinlọgọta l’awọn ọmọ naa lo l’akata awọn ajinigbe, wọn maa nilo amojuto gidi nitori ohun ti oju wọn ti ri.

Femi ni, gomina jade wa sọ pe b’oun ṣe kede pe oun n lọ fun ipo aarẹ ni aago mẹrin irọlẹ, aago mẹsan ọjọ keji ni iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ, eyi to n tọka si pe ere oṣelu ni iṣẹlẹ naa.

O ni oun o fi ọrọ gun tabi wọ ẹnikẹni ni’lẹ, ni ṣe l’oun n ra’wọ ẹbẹ pe ki a fi awọn ọmọde silẹ ninu gbogbo ọrọ ti o ba oju mu to n ṣẹlẹ l’orile-ẹde yii.

L’ana ni awọn olukọ ati akẹkọọ ti wọn jigbe ni ijọba ibilẹ Oriire nipinlẹ Ọyọ gba itusilẹ lẹyin ọjọ mẹrindinlọgọta ti wọn ti wa ni ahamọ.

 

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search