MC Oluọmọ ati Baruwa Da Ija’gboro L’Abuja L’ori Ipo Ọga Onimọto

Nṣe ni ọrọ di bo-o-lọ-o-ya-n-mi ni igboro ilu Abuja, nigba ti Tajudeen Baruwa ati ikọ rẹ gbakoso olu-ile ẹgbẹ ọlọkọ ero NURTW to wa nilu Abuja kuro l’ọwọ Musiliu Akinsanya ti ọpọ mọ si MC Oluọmọ ati awọn ikọ ti ẹ naa.

L’oni l’asiko Baruwa ati awọn eniyan rẹ yabo ile ẹgbẹ naa lo n ṣalaye f’awọn oniroyin pe aṣẹ ile ẹjọ ni awọn wa mu ṣe, nitori idajọ meji ọtọtọ lati ile-ẹjọ lo da awọn l’are l’ori ẹjọ taa ni ipo aarẹ ẹgbẹ naṣana (NURTW) wa l’ọwọ rẹ l’aarin Baruwa ati Oluọmọ.

Siwaju si, Baruwa ṣ’aleye pe awọn ti fi ọrọ to awọn agbofinro leti botilẹjẹ pe wọn ko kọ’bi ara to nnkan s’awọn ṣugbọn t’awọn ti jẹ ko di mimọ pe ilana pẹlẹ kutu ni awọn fi fẹ gba akoso ohun to tọ si wọn lẹyin ti awọn ti ni suuru fun bi ọdun meji t’oun ti pe ile-ẹjọ oṣiṣẹ ati ti kotẹmilọrun da’wọn l’are botilẹjẹ pe Oluọmọ ati awọn eniyan rẹ kọ eti ọgbọin.

L’ẹyin wakati diẹ ti gbogbo eyi ṣẹlẹ tan lo tun to’ni leti pe awọn ọlọpa ti pada wa fi kele ofin gbe Baruwa gan-an bayii fun gbigba akoso olu-ile ẹgbẹ naa lọna ti ko tọ.

Awuyewuye ti pọ pupọ l’ori faa-ka-ja ọrọ lati bi ọdun diẹ ti igun mejeeji ti jọ n na tan bi owo l’ori taa ni ojulowo aarẹ ẹgbẹ awakọ ero NURTW ni orilẹ-ede Naijiria. ‘Eegun Alare’ – ọrọ n ba ọrọ bọ.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search