Ori ayelujara Naija lo ti n darudapọ l’ẹnu l’ọwọlọwọ yii l’ori ohun (WhatsApp voice note) to n ja ranyin-ranyin kaakiri l’ori ayelujara eleyii ti wọn pe ohun Aarẹ Bọla Tinubu ni ohun naa, to si mẹnuba awọn ọrọ pataki nipa iṣoro eto aabo to daamu orilẹ-ede Naijiria l’ọwọ yii.
Ohun to jẹ ki ọrọ naa le ni pe agbẹnusọ Aarẹ Tinubu, Bayọ Ọnanuga bọ si’ta ṣ’aleye pe agbelẹrọ patapata ni ohun naa, ti kii ṣe ti Aarẹ Tinubu rara, to si tun fi ẹsun kan gbajugbaja ajijangbara, VeryDarkMan (VDM) pe oun lo lu ohun agbelẹrọ naa si’ta lati ṣi awọn eniyan lọna. Ọnanuga le’ri pe dandan ni ki VDM koju ofin l’ori iwa to fi ẹsun rẹ kan han.
Amọ ṣa, ọrọ naa ko tutu rara, igbona-gbooru ti ọrọ naa wa ni VDM fi fọ esi buruku pada lati orilẹ-ede China to wa bayii fun Ọnanuga pe “omugọ alairelo ẹda ni Ọnanuga bii gbogbo awọn to ku to n ṣiṣẹ labẹ ijọba Tinubu.”
VDM tẹsiwaju pe ọpọlọpọ ipe l’oun ti ri gba l’ori ọrọ naa ki oun ti ẹ to mọ ohunkohun ṣugbọn to ni oun ta Ọnanuga ati ijọba Tinubu l’aya lati fi ọwọ ofin mu oun l’ori ẹsun naa pe ki wọn o fi idi rẹ mu’lẹ pe lootọ l’oun lu ohun (voice note) na foto si awujọ.
Ẹwẹ, gbajumọ agbẹjọro, Deji Adeyanju to jẹ agbẹjọro fun VDM naa ti jade sọrọ pe onibara oun ko gbe ohun (voice note) kankan to jọ eyi ti Ọnanuga n sọ loju opo ayelujara rẹ kankan.
Siwaju si, VDM jẹ ko di mimọ pe wọn ko le pa ohun mọ agogo ohun lẹnu lati ma mẹnuba awọn iṣoro eto aabo to wa ni orilẹ-ede Naijiria.
Oniruuru awọn eniyan lo ti wa n jẹ awuyewuye naa l’ẹnu, awọn kan n pe VDM ko ṣe gbe ti mọ’le nitori wahala nla ni yoo bi ṣugbọn ti awọn miiran n sọ pe bi ọrọ naa ba ri bi Ọnanuga ti wi, n ṣe lo yẹ ki VDM o ka’wọ pọn’yin ro’jọ ni’waju ofin nitori ofin ga ju ẹnikẹni lọ.