Minisita f’ọrọ ohun amusagbara, Adebayọ Adelabu ti tọrọ aforijin lọwọ awọn ọmọ orilẹ-ede Naijiria l’ori bi ina ọba ṣe dagbere ni ọpọ agbegbe yika orilẹ-ede Naijiria lati igba diẹ s’ẹyin, l’eyi to ti ṣe akoba nla fun awọn ile’gbe, okoowo, ati ile-iṣẹ loriṣiriṣi.
Nigba to n s’ọrọ l’oni ọjọ Iṣẹgun Tuesday nilu Abuja, Adelabu gba pe aisi ina ọba ti mu ki nnkan burẹkẹ si f’awọn ọmọ Naija paapaa julọ pẹlu bi ooru ṣe n mu pupọ ju l’asiko yii.
O ṣ’alaye pe, awọn iṣoro kọọkan to j’ara lọ bi iṣoro ati ri afẹfẹ gaasi ati akude to ba awọn ẹrọ lo ṣokunfa bi ina ọba ṣe poora l’ọpọ agbegbe ṣugbọn to jẹ pe awọn ti n m’oju to, ti ara ilu yoo si bẹrẹ si ni ri iyatọ laipẹ.
“Mo le sọ fun yin pe awọn igbimọ ti iṣẹ wa l’ọwọ wọn ti n ṣiṣẹ l’ori ati yanju ọrọ yii, awọn onigaasi naa ti ṣe’leri ifọwọsowọpọ. Ni nnkan ọsẹ meji si asiko yii, ayipada rere yoo ti ma farahan l’ori ipese ina ọba.” Ni’pari, Adebalu tọrọ aforijin lọwọ awọn ọmọ ilẹ yii pẹlu idaniloju pe igbiyanju lati wa ojutu si iṣoro ina ọba ti n lọ l’ọwọ, ti ayipada rere yoo si tẹle laipẹ.