Ẹ Ma Pe Wa Ni Olorin Anaa – Esther Igbẹkẹle Pariwo Si’ta

Gbajugbaja olorin ẹmi ti orin rẹ ma n mu agbara dani – Esther Igbẹkẹle, lo ti pa’riwo si’ta pe ki awọn ololufẹ orin ẹmi o ma pe iru awọn t’awọn ti di agba ọjẹ ni’di iṣẹ orin ẹmi ni olorin anaa nitori awọn olorin ẹmi tuntun.

Ninu atẹjade pataki kan ti olorin naa fi si’ta l’oju opo ikanni Facebook rẹ lo ti fi ẹdun ọkan rẹ han si aṣa ari’yawo kọ iyalẹ ti awọn ololufẹ orin ẹmi fẹ ma da.

Igbẹkẹle jẹ ko di mimọ pe ohun to dun ni jọjọ ni lati ri ki awọn ololufẹ orin ẹmi ma kọ awile (comment) s’abẹ orin awọn olorin ẹmi tuntun pe “ẹyin la n gbọ l’ọwọ yii, k’awọn t’anaa lo sinmi.

“Ṣe nitori pe o jẹ orin ẹmi ni awọn eniyan ko ṣe ka iru ọrọ bẹẹ si. O yẹ ki awọn eniyan ma a fi ọrọ ṣiro ara wọn.”

Siwaju, igbẹkẹle ni ohun ti ko dara ni lati ma kọ iyan awọn olorin t’aye ti mọ tẹlẹ kere nitori awọn olorin tun.”Bi orin tuntun ba dun l’eti yin bi pe ẹ gbọ iru rẹ ri, iyẹn o sọ awọn olorin to ti wa tẹlẹ di alaimọọṣe nitori awọn ni wọn gbe iṣẹ naa l’arugẹ bọ lat’ẹyin… Titi aye ni orin tuntun ati olorin tuntun a maa ja’de.”

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search