Pẹlu omije l’oju ni oṣerebinrin nni, Damilọla Adekọya ti ọpọ mọ si Princess Comedian fi n bu epe jo gbajugbaja oṣere tiata nni, Biọla Adebayọ to tun jẹ olootu eto “Talk to B” l’ori ọrọ oṣere ati alawada, Lanre Omiyanka ti ọpọ mọ si Baba Ijẹṣa.
Ẹ ranti pe ori eto Biọla jẹ ọkan pataki ninu awọn aaye ifọrọwerọ ti Baba Ijẹṣa ti lọ kopa lati sọ abala ti ẹ l’ẹyin to t’ẹwọn de l’ori ọran jijẹbi ẹsun ibalopọ kotọ pẹlu ọmọ kekere kan to wa ni akata Princess l’eyi to pada di wahala nla.
Ninu fọnran kan ti Princess ṣe lati fi aidunnu rẹ han si bi Biọla ti gba Baba Ijẹṣa l’alejo lati wa sọ t’ẹnu rẹ l’ori gbogbo ohun to ti ṣẹlẹ naa, ti Princess si d’ẹbi ru Biọla pe o n fi igi gun oju ọgbẹ oun ati pe ko ka awọn ọmọ kekeke to ti lu’gbadi iwa Baba Ijẹṣa kun.
Ẹwẹ, ṣaaju ni Biọla Adebayọ ti ja’de lati tọrọ aforijin l’ọwọ awọn eniyan l’ori alejo Baba Ijẹṣa to gba ṣugbọn ti Princess ko fi ọwọ wọ’nu. Oniruuru awọn eniyan lo ti wa n p’ẹkẹ lu ọrọ naa pe kinni Princess tun fẹ, bẹẹ ni awọn kan n pe arokan lo n fa ẹkun asun-n-da fun Princess nitori ọgbẹ nla ti ọrọ naa ti da si lọkan.