Zulum Gboriyin Fun Ikọ Ọmọ Ologun Ilẹ Wa Fun Idoola Awọn Ọtalelọọdunrun Ni Borno

Gomina ipinlẹ Borno, Babagana Zulum ti ṣe sadankata fun awọn ọmọ ologun ilẹ wa paapaa julọ ikọ Operation HADIN KAI fun bi wọn ṣe doola awọn ọtalelọọdunrun (360) kuro ninu ori oke Mandara to jẹ ibi isadi f’awọn ẹlẹkẹru agbesunmọmi ni ẹkun guusu ipinlẹ naa.

Zulum lo kọkọ lọ ṣabẹwo si awọn eeyan Ngoshe ni ọjọ kẹfa oṣu kẹta ọdun yii to si lọ sun ti awọn araalu Pulka nijọba ibilẹ Gwoza nibi to ti fi wọn lọkan balẹ pe iṣejọba oun ati ijọba apapọ n ṣiṣẹ takuntakun lati doola awọn ti wọn ṣi wa ni ahamọ awọn ajinigbe.

Ninu atẹjade kan ti oludamọran pataki lori iroyin Dauda Iliya buwọlu ni gomina ti ṣapejuwe akanṣe iṣẹ naa gẹgẹ bii eyi to ṣafihan igboya, ifọkansiṣẹ ati igbooro iṣẹ ọpọlọ lati mu opin de ba igbesunmọmi ni ẹkun ariwa ila-oorun.

Gomina Zulum ni akanṣe iṣẹ naa leyi to mu ki wọn doola ọpọ ọkunrin, obinrin ati ọmọde ti wọn wa ni ahamọ awọn ajinigbe lo ti mu ireti ọtun ba awọn agbegbe naa to si n fi wọn lọkan balẹ pe ijọba apapọ, ijoba ipinlẹ Borno ati awọn ọmọ ologun ilẹ wa ṣetan lati daabobo awọn araalu ati lati da alaafia pada si ẹkun naa.

O wa dupẹ lọwọ Aarẹ Bọla Tinubu, Ọga agba fun Ile-iṣẹ eleto-aabo, Ọga agba fun Ile-iṣẹ ọmọ-ogun ori-ilẹ, Ọgagun awọn ikọ Hadin Kai ati gbogbo awọn ọmọ ologun ti wọn kopa ninu iṣẹ idoola na bẹẹ lo gboriyin fun awọn araalu fun ifọwọsowọpọ wọn.

O tẹsiwaju lati rọ awọn ara agbegbe Mussa ni ijọba ibilẹ Askira Uba lati ma sọ ireti nu nitori ijọba n gbiyanju lati doola awọn ọmọ ile-iwe ti wọn ko lọ l’agbegbe naa.

Zulum wa rọ awọn araalu lati ranti pe oju ni alakan fi n ṣọri ki wọn si ma kuna lati fun ijọba ati awọn ẹṣọ alaabo ni awọn iroyin to le f’opin si iṣẹ ọdaran nipinlẹ naa.

Ipinlẹ Borno lo jẹ aarin gbungbun ibi ti igbesunmọmi ti gbongun julọ lorilẹede Naijira lati ọdun 2011 ti ọpọlọpọ ẹmi si ti baa lọ.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search