Peter Obi Pe Tinubu L’ọdaju Adari L’ori Ọrọ Ilu Jos

Ọkan pataki ninu awọn to n tiraka lati de ipo Aarẹ orilẹ-ede Naijiria – Ọgbẹni Peter Obi to tun jẹ Gomina tẹlẹ nipinlẹ Anambra ti s’ọrọ nipa abẹwo Aarẹ Bọla Tinubu si awọn eniyan ti ikọlu wa’ye si ni agbegbe Angwar Rukuba ni’jọba ibilẹ Ariwa Jos.
Peter Obi ninu atẹjade ọrọ kan to fi le’de l’ori ayelujara ni oju opo X lo ti tọ’ka si pe abẹwo ti Aarẹ ṣe ọhun ti fi han pe Bọla Tinubu ko ni aanu ọmọniyan l’oju rara ati pe ko si idari rere to ka awọn ọmọ Naija kun rara.

Obi f’ẹsun kan Tinubu pe ko naani awọn eniyan naa rara pẹlu bo ṣe fi ipade pẹlu awọn eniyan naa si papakọ ofurufu to wa niluu Jos dipo ko lọ si’nu ilu ti ikọlu naa ti wa’ye gan-an ni pato lati ba wọn kẹdun. Ẹwẹ, Obi tọ’ka si iṣẹlẹ ikọlu ilu Yelwata nipinlẹ Benue pe bakanna ni pẹlu bi Tinubu ko ṣe kọja ile ijọba ipinlẹ Benue nigba naa ti ko si f’ẹsẹ tẹ ilu Yelwata rara.

Siwaju si, Obi jẹ ko di mimọ pe awọn ọmọ orilẹ-ede nilo adari ti yo ni ẹyin’ju aanu fun ara ilu. Eefin ina awuyewuye ọrọ yii ṣi n sọ lala l’aarin ilu, l’aarin iwoye to ṣ’ọtọtọ, awọn kan gba pe Tinubu ti ṣe ẹtọ pẹlu ṣiṣe abẹwo naa ati pe ileri ati sọ igba d’ẹrọ fun wọn ṣugbọn ti awọn kan gbagbọ pe Aarẹ Tinubu ko ṣe daadaa to l’ori amojuto iṣẹlẹ naa.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search