Oṣere, Kunle Afod Ko Gomina Aiyedatiwa ati Awọn Oloṣelu Ondo Si’ta Bi Ọmọ’jọmẹjọ

Oṣere, Kunle Afod Ko Gomina Aiyedatiwa ati Awọn Oloṣelu Ondo Si’ta Bi Ọmọ’jọmẹjọ

Gbajugbaja oṣere tiata, Kunle Afọdunrin ti ọpọ mọ si Kunle Afod lo ti bẹrẹ si ni ke’bosi orukọ gomina ipinlẹ Ondo, Lucky Orimisan Aiyedatiwa ati awọn oloṣelu kọọkan ni ijọba ibilẹ Ọsẹ nipinlẹ Ondo l’ori ipo ti ko b’oju ri ti agbegbe naa wa l’odidi. Oṣere naa ninu awọn fọnran to ti ṣe s’ẹyin lo ti n pe akiyesi awọn oloṣelu t’ọrọ kan ni agbegbe ijọba ibilẹ Ọsẹ lati tete wa nnkan ṣe si bi ọpọ nnkan ti pakasọ ni agbegbe naa.

Ọrọ oju ọna to buru jai ni oṣere naa kọkọ mu mọ ẹnu, pe ko fẹ si ọna kankan to bu’yi kun’yan ni gbogbo agbegbe naa. Ni’gba to ya, Kunle Afod, mu ọrọ ina ọba to ti dagbere ni adugbo naa lati aimọye ọdun s’ẹyin mọ, ati bi ọpọ ile-ẹkọ to wa l’agbegbe naa ṣe ti d’ẹnu kọ’le patapata.

Si’waju si, Kunle Afod nibamu pẹlu ileri rẹ ninu awọn fọnran ikilọ to ti kọ ṣe ṣaaju pe, ti oun ko ba ri esi rere gba l’ori awọn akiyesi naa, pe oun yoo bẹrẹ si ni da orukọ wọn, bẹrẹ lati ori gomina, to fi mọ awọn oloṣelu miran t’ọrọ kan gbọngbọn bi alaga ijọba ibilẹ Ọsẹ; awọn aṣoju nile aṣofin apapọ ati ti ipinlẹ. Lara awọn ti oṣere naa pe si’ta ni Clement Kolapo Ojo; Olatunji Emmanuel Oshati; Adelegbe Oluwatimehin Emmanuel; Ipinsagba Emmanuel Olajide ati Gomina Lucky Orimisan Aiyedatiwa.

Ni ipari, Kunle Afod ni oun ko ni jawọ ati ma pe akiyesi awọn oloṣelu t’ọrọ kan titi di igba ti iyatọ ọtun ba de si agbegbe ijọba ibilẹ ti o n mẹnuba naa.

Gbajúgbajà òṣèré tíátà ní Azubuike Michael ti gbogbo èèyàn …

Gbajugbaja oṣere, Tobi Makinde ti ọpọ mọ si “Tirinrin” …

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search