Gbajugbaja oṣere, Tobi Makinde ti ọpọ mọ si “Tirinrin” ti jade ṣalaye pe ko si aawọ abi ija kankan laarin oun ati irawọ onisinima, Funkẹ Akindele. O juwe pe ahesọ awọn onirikiṣi lasan ni pe ija kankan wa laarin awọn mejeeji. Tobi lo sọ eyi ninu ifọrọwerọ kan to ṣe laipẹ yii pẹlu ikanni BBC Yoruba. Nibẹ lo ti la mọlẹ pe kosi wahala kankan rara laarin oun ati ọga oun tẹlẹ, iyẹn Funkẹ ṣugbọn, ti ọpọn iṣẹ oun ti sun siwaju si lo fa bi wọn ko ṣe ri awọn mejeeji pọ da bi ti tẹlẹ.
O ṣalaye siwaju si pe, Funkẹ ko le wa si ibi igbeyawo oun nitori pe o bọ si asiko ti Funkẹ polowo sinima tuntun kiri, ti gbogbo aye si mọ pe Funkẹ ki fi iṣẹ rẹ ṣawada. Ko ṣai mẹnuba pe ọdun 1998 loun ti bẹrẹ iṣẹ ere lati ọmọ ọdun meje, nipasẹ baba rẹ, Jimi Makinde ati gbajugbaja agbesinima jade Ọgbẹni Tunji Bamishigbin. Lẹhin ti Funkẹ Akindele naa wa pada ko ipa to jọju nigba ti asiko to.
O pari ọrọ rẹ pe, ibaṣepọ oun ati Funkẹ ko bẹrẹ lori ayelujara, ko dẹ le pari sibẹ. “Mo le lọ ba Arabinrin Funkẹ Akindele ṣiṣẹ ti wọn ba pe mi, bẹẹ emi naa le wọn si iṣẹ ti aye rẹ ba yọ.” Amọ ṣa, iṣẹ ti sun oun si iwaju lọwọ yii, ti oun naa si ti bẹrẹ gbigbe sinima ararẹ jade.