Trump Sọrọ Kobakungbe Si Poopu Leo ti Ijọ Aguda

Aarẹ orilẹ-ede Amẹrika, Donald Trump lo ti sọrọ buruku si olori ijọ Aguda lagbaye, Pope Leo kẹrinla lori ogun to n lọ lọwọ laarin orilẹ-ede Iran ati iparapọ Amẹrika ati Israel.

Ninu atẹjade kan ti Trump gbe jade lori ikanni Truth lo ti pe Poopu Leo ni ojo, ati alailoye nipa ọrọ oṣelu agbaye. Trump ṣalaye ninu atẹjade naa pe o ko gba ti Leo bi ti wu ko mọ, dipo bẹẹ, oun gba fun Poopu anaa, Louis, nitori ti iyẹn mọ ọwọ wẹ daadaa.

Trump tun mẹnuba pe oun mọ pe ijọ Aguda mọọmọ yan Leo lati orilẹ-ede Amẹrika lati le gbena woju oun ni ṣugbọn ti Leo ko to iṣẹ naa jẹ.

” Nko gba ti Leo rara, un o mu Louis dipo rẹ. N ko fẹ Poopu ti ko ri aburu ninu ki orilẹ-ede Iran o ni ohun ija apanirun. N ko fẹ Poopu ti ko ni dunnu si bi Amẹrika ti kọlu orilẹ-ede Venezuela fun awọn iwa ẹsẹ wọn.” Eyi jẹ diẹ ninu awọn ohun ti Trump tọka si ti Leo ko fi gbayi niwaju rẹ.

Ẹwẹ, Poopu Leo ni tiẹ, ẹni to n ṣabẹwo lọwọ si orilẹ-ede Algeria, leyi to jẹ akọkọ iru rẹ si ilẹ adulawọ lati igba to ti de ipo ti fesi loni ọjọ Aje lori ọrọ yii pe “n ko ni esi abi itakurọsọ kankan fun Trump nitori ti emi ki kii ṣe oloṣelu. Ọrọ alaafia lagbaye nikan lo ba mi.”

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search