Ori Yọ B-Red Ọmọ Gomina Adeleke L’ọwọ Iku Lat’ọwọ Awọn Janduku L’Ọṣun

Ọmọ Gomina Ademọla Adeleke ti ipinlẹ Ọṣun, to tun jẹ gbajugbaja onkọrin, Adebayọ Adeleke to ọpọ mọ si B-Red ni ori ko yọ lọwọ awọn janduku ẹda kan to gbiyanju lati da ẹmi rẹ legbodo ni igboro ilu Oṣogbo to jẹ olu-ilu ipinle Ọṣun.

Ikọlu naa ni B-Red jẹ ko di mimọ pe o waye ni nnkan ọsan Ọjọru (Wednesday) anaa lagbegbe Oke-Fia niluu Oṣogbo.

Ninu alaye rẹ, B-Red jẹ ko di mimọ pe awọn to ṣe ikọlu naa fi alupupu okada le ọkọ rẹ pẹlu fila “Ambo” tii ṣe oludije sipo gomina ninu ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Ọṣun lori wọn. Bẹẹ lo tun darukọ ọmọ iṣọta kan ti ọpọ mọ si Aṣiri Ẹniba gẹgẹ bii ọkan ninu awọn to ṣe ikọlu naa, ti wọn si le oun digba digba de ẹnu iloro ile ijọba.

L’ọwọ yii, B-Red ṣalaye pe oun ti fi ọrọ naa to awọn agbofinro leti ti iṣẹ iwadii yoo si wa’ye lori iṣẹlẹ naa.

Ẹwẹ, ẹ ranti pe eto idibo gomina ni ipinlẹ Ọṣun ti sunmọ lati waye ninu oṣu kẹjọ (August), ti Gomina Ademọla ati Ambo si jẹ ọkan pataki ninu awọn oludije.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search