Ile-ẹjọ Giga Julọ Ti Yọ Turaki Ni’gun Gomina Makinde Kuro Nipo Alaga Ẹgbẹ PDP

Ile-ẹjọ to gaju lọ lorilẹede Naijira ti wọgi le apejọpọ Ẹgbẹ Oṣelu PDP to waye nilu Ibadan nipinlẹ Ọyọ ni ọjọ kẹrinla ati ikẹẹdogun oṣu kọkanla Ọdun to kọja. Eyi ti fa ifasẹyin fun igun inu ẹgbẹ naa ti Tanimu Turaki n lewaju fun.

Ninu idajọ ẹlẹni marun ni awọn adajọ agba mẹta ti fi ontẹ lu idajọ Ile-ẹjọ Giga ati ti Ile-ẹjọ ko tẹmilọrun to fi ofin de ipejọpọ naa. Adajọ Agba Stephen Adah nigba to n gbe idajọ naa kalẹ sọ pe awọn olupejọ naa kọ lati tẹle idajọ ti Ile-ẹjọ Giga to ni ki wọn ṣe ipejọpọ naa to si fa irufin.

Ile-ẹjọ naa fikun pe awọn faramọ esi ti awọn ile-ẹjọ keekeke ti wọn ti kọkọ gbejọ naa lọ fi nitori lootọ ni igun naa tọwọ bọ ofin loju pẹlu bi wọn ṣe tẹsiwaju lori ipejọpọ wọn lẹyin ti Ile-ẹjọ ti da wọn l’ẹkun.

Ipejọ yii lo tẹle idajọ ti Ile-ẹjọ kotẹmilọrun ti wọn da ni Ọjọ Kẹsan Oṣu Kẹta ọdun yii eyi to wọgi le ipejọpọ ẹgbẹ oṣelu naa to si rọ Ajọ to n ṣeto idibo nilẹ wa lati ma fi ontẹ lu esi abajade ipejọpọ naa.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search