Mejila ninu awọn ọmọ ọrinlenigbadinmẹrin ti wọn jigbe ni ile-iwe girama Government Girls Secondary School to wa lagbegbe Chibok ni Ipinlẹ Borno ni wọn ti n mura ati jade Ile-iwe Giga bayi lẹyin ọdun mejila ti iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ.
Nigba to n sọrọ lọgba ile-iwe giga naa, American University of Nigeria to wa nipinlẹ Yola, Aarẹ Ile-iwe naa Dewayne Frazier ṣapejuwe akoko naa gẹgẹ bi akoko ijawe olubori.
O ṣalaye pe aṣeyọri awọn ọmọ ọun lati inu igbo Sambisa debi ti wọn wa leni kii ṣe ti ẹkọ nikan nitori pe o ṣe afihan pe aforiti, ireti ati igboya ọkan.
O tẹsiwaju pe awọn ọmọ naa ti di ẹni ajitanna wo ati awokọṣe rere fawọn ara Ariwa ati gbogbo Agbaye lapapọ nitori aṣeyọri yii tọka si pe ẹkọ ṣe pataki, o si ṣe koko fun imugbooro Orilẹede Naijiria. Frazier wa gboriyin fun Ile-iṣẹ ijọba to n risi Ọrọ Awọn Obinrin fun atilẹyin wọn lori owo ile-ẹkọ awọn ọmọ naa.
Ti ẹ o ba gbagbe, Ọjọ kẹrindinlogun oṣu kẹrin ọdun 2014 ni ikọ agbesunmọmi Boko Haram ṣe ikọlu si Ile-ẹkọ Government Girls Secondary School to wa lagbegbe Chibok ni Ipinlẹ Borno ti wọn si ko awọn ọmọ ọrinlenigbadinmẹrin. Ninu awọn ọmọ naa ni mẹtadinlọgọta raye sa mọ wọn lọwọ loru ọjọ naa ti wọn si doola ẹmi ọpọlọpọ bi ọdun ṣe n gori ọdun bi o tilẹ jẹ pe wọn ṣi n wa awọn ọgọrin titi di isinyi.