Idunnu Ṣubu Layọ Fun Ẹbi Gbajugbaja Olorin Fuji, Pasuma Bi Ọmọ Rẹ Ṣe Bímọ L’Amẹrika

Iro idunnu sọ lagboole gbajugbaja olorin Fuji nni, Wasiu Alabi ti gbogbo eeyan mọ si Pasuma bi ọmọ rẹ obinrin Opeyemi Ololade ṣe bi ọmọ ọkunrin lanti lanti nilu Amẹrika.

Olorin ọun lo fi idunnu rẹ han lori itakun ibanidọrẹ Instagram rẹ nibi to ti n ki ara rẹ ati ọmọ rẹ ku oriire. O ni “Mo ki ara mi ku oriire, ọmọ mi Opeyemi Ololade to jẹ ọmọ Ikọ Ologun Ori Omi lorilẹede Amẹrika ti bi ọmọ ọkunrin lana nilu Amẹrika. Ọmọ ologun imi ti kun ẹbi mi. Mo dupẹ lọwọ Ọlọrun. O mu ori mi wu ọmọ mii.

Pasuma ati Omo

Ọpọlọpọ awọn gbajumọ oṣere ati awọn ololufẹ ni wọn ti ba dawọ idunnu lori ọmọ-ọmọ rẹ. Awọn oṣere bii Muyiwa Ademola, Fathia Balogun, Madam Saje, Kamo State ati bẹẹ bẹẹ lọ ni wọn wa lara awọn ti wọn ba olorin naa ati awọn ẹbi ẹ yọ ayọ ọmọ tuntun naa.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search