Ilumọọka sọrọ-sọrọ to jẹ atọkun eto “Who wants to be a millionaire” ti gbogbo eeyan nifẹsi lori ẹrọ amohunmaworan ni bi ọdun melo kan sẹyin, Frank Edoho lo ti jade wa sọrọ lori igbeyawo elekeji rẹ to fori ṣọpọn l’ọdun to kọja.
Ninu ọrọ kan to fi lede lori itakun ibanidọrẹ Instagram rẹ lo ti sọ pe oun ti fi ọrọ ipinya pẹlu iyawo oun ṣe osun para ni kọrọ ṣugbọn ni bayi o ti de ibi ti oun ti gba kamu lori ọrọ naa.
Edoho dupẹ pupọ lọwọ awọn ololufẹ rẹ fun atilẹyin wọn pẹlu adura ati ọrọ itunu ti wọn fi ranṣẹ sii ni gbogbo igba latigba ti ọrọ naa ti ṣẹlẹ.
O ṣalaye pe bi o tilẹ jẹ pe ọpọlọpọ awọn eeyan ṣẹṣẹ n mọ si nigboro, oun ti n ba ọrọ naa fa lati bi ọdun meji ti oun si ti pada ni ibalẹ ọkan lẹyin gbogbo rogbodiyan naa.
O tẹsiwaju lati sọ pe oun nigbagbọ pe igba oriṣiriṣi lo wa laye ati pe nigba mii o san ki eeyan tẹ siwaju lai ni ariwo ninu. O fikun pe lọwọ yii oun ti wa lalaafia pẹlu ibalẹ ọkan.
Edoho lo ti kọkọ fẹ Katherine Obiang to jẹ agbohunsafefe ni ọdun 2003 ki wọn to pinya ni ọdun 2010 lẹyin ọmọ mẹta. Lẹyin naa lo fẹ Sandra Onyenuchenuya ni ọdun 2013 to bi ọmọ meji fun. Iroyin ipinya Edoho ati Sandra jade ninu oṣu kẹfa ọdun to kọja.
Ẹnu ọjọ mẹta yii ni awuyewuye bẹrẹ lori ohun to fa ituka wọn latari awọn ọrọ Edoho lori ọrọ ayelujara lẹyin ti o jade lori itakun ibanidọrẹ X rẹ. Laipẹ yii lo fi ọrọ lede pe oun ko le fi ọkan si ọdọ obinrin kankan mọ bẹẹ lo n ṣe ikilọ fun awọn ọkunrin lati ma foriji obinrin to ba fi ọbẹ ẹyin jẹ wọn n’iṣu. Awọn ọrọ yii lo fa ti ọpọlọpọ fi gba lero pe ọrọ yiyan ale lo da aarin wọn ru.
Ọrọ ti Edoho fi lede yii ti wa fihan gbangba pe ohun to fa ituka naa kii ṣe kekere.