Aburo Siminalayi Fubara Jade Lati Dije Dupo Gomina Ipinlẹ Rivers Labẹ Asia Ẹgbẹ Oṣelu NDC

Ambassador Blessing Fubara Senior to jẹ aburo l’ọkunrin fun gomina ipinlẹ Rivers Siminalayi Fubara, lo ti fi erongba rẹ han lati dije dupo gomina labẹ asia ẹgbẹ oṣelu NDC to si n ṣeleri pe oun o ni lo ju saa kan lọ.

O sọ eyi ni igbaradi fun eto idibo abẹle ẹgbẹ oṣelu naa to so n ṣapejuwe ara rẹ gẹgẹ bii ẹni to ti ṣetan to si koju oṣuwọn lati da alaafia pada ati ṣe atunṣe si eto ọrọ aje ipinlẹ naa.

O ṣalaye pe ipinlẹ naa ti koju ifasẹyin lori eto ọrọ aje to si n pe fun atunto lẹka oṣelu. Fubara fi aidunnu rẹ han lori bi oṣelu ṣe n lọ nipinlẹ Rivers nitori o ti fa ifasẹyin fun ipinlẹ naa.

O ṣalaye pe ipinlẹ naa ti koju ifasẹyin lori eto ọrọ aje to si n pe fun atunto lẹka oṣelu. Fubara fi aidunnu rẹ han lori bi oṣelu ṣe n lọ nipinlẹ Rivers nitori o ti fa ifasẹyin fun ipinlẹ naa.

O sọrọ lori bi ipinlẹ naa ṣe ti padanu anfaani lọpọlọpọ bẹẹ lo sọ pe o yẹ ki ẹkun guusu ila-oorun pari saa ọdun mẹjọ ki ẹkun mii to wọle.

O wa pe awọn alatilẹyin rẹ to ni wọn le ni miliọnu meji lati tii lẹyin to si n fi ọkan awọn eeyan balẹ pe saa kan pere l’oun maa lo.

Fubara wa ke pe ẹgbọn rẹ pe asiko ti to fun lati sun sẹyin fun oun nitori ilọsiwaju ipinlẹ Rivers.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search