Gbajumọ alafẹ Cubana Chief Priest ti tẹnpẹlẹ mọ pe iṣootọ oun pẹlu Aarẹ Bola Tinubu ati ẹgbẹ oṣelu APC ko ṣee mi bẹẹni ko ṣee pakuta si lai fi ti awọn ifasẹyin oṣelu to koju nipinlẹ Imo.
Nigba to n sọrọ nibi ifọrọwanilẹnuwo kan, olokoowo naa wọgi le awọn ero pe ijakulẹ to ni lati gba tikẹti ẹgbẹ naa ti ba ajọṣepọ oun ati ẹgbẹ naa jẹ.
Cubana Chief priest to padanu tikẹti ẹgbẹ oṣelu APC lati ṣoju ẹkun ila-oorun Orsu/Orlu/Oru ipinlẹ Imo ni ile igbimọ aṣojuṣofin lo ti wa yan-na yan-na awọn ọrọ to yi ọjọ ọla rẹ ninu oṣelu ka t’oun ti ifọkanji fun ẹgbẹ naa lẹyin eto idibo abẹnu wọn.
Sanmọri ọhun to ṣiṣẹ fun ajọ City Boy Movement ẹka ti ẹkun guusu ila-oorun leyi ti wọn fi n polongo fun Aarẹ Tinubu fun idibo ọdun 2027 lo ti sọ pe atilẹyin oun fun Aarẹ ṣi wa dọindọin lai si ohun to le yẹ.
O tẹsiwaju pe ipinnu oun lati ṣe ijọba da le ifẹ ọkan oun lati kopa ninu iṣelu yatọ si ọrọ ori ẹrọ ayelujara lasan. Gẹgẹ bo ṣe wi, o ni oun ni ọwọja, iriri ati gbogbo nkan ini ti yoo wulo ninu oṣelu.
Cubana wa tọka si awọn imugbooro to ti de’ba ipinlẹ Imo leyi to mu ki oun ṣatilẹyin fun iṣejọba APC bẹẹ lo sọ pe awọn gomina ni owo to t’owo lọwọ fun idagbasoke awọn ipinlẹ nitori owo iranwọ ori epo ti ijọba yọ.
Ni ibẹrẹ oṣu yii ni alafẹ naa sun sẹyin nibi idije idibo abẹle lẹyin ifọrọwọrọ pẹlu awọn agbaagba ẹgbẹ leyi to fi han pe asiko o tii to fun ijọba ibilẹ rẹ.
Ti ẹ o ba gbagbe lori ẹrọ ayelujara laipẹ yii ni Cubana chief priest ti sọ pe Aarẹ Tinubu o tii f’ọkan tan oun nitori atilẹyin t’oun fun Peter Obi ni ọdun 2023.