Aarẹ-Ọna Kakanfo ilẹ Yoruba, Oloye Iba Gani Adams lo ti kọminu lori ipo ti eto aabo wa nilẹ yii, to si n tọka si pe awọn agbesunmọmi ti wọ awọn ijọba ibilẹ bi ogoji (40) ni ẹkun iwọ-oorun guusu (Southwest).
Ninu ifọrọwerọ kan to ṣe laipẹ yii lo ti jẹ ko di mimọ pe iṣoro eto aabo to wa ni ẹkun naa buru pupọ ju ohun ti awọn eniyan l’ero lọ.
O ṣ’aleye pe, iwadii ti ikọ rẹ ṣe yika gbogbo ijọba ibilẹ metadinlogoje (137) to wa ni ẹkun iwọ-oorun guusu (Southwest) lo fi oju okodoro ọrọ han.
“Kekere kọ ni iye onka awọn agbesunmọmi ti a kẹfin, wọn pọ pupọ yika awọn ijọba ibilẹ ti ko din ni ogun.”
Aarẹ-Ọna tun jẹ ko di mimọ pe esi iwadii awọn ni awọn kọkọ fi pamọ si ọwọ awọn gomina nikan lati tete gbe igbesẹ to yẹ ṣugbọn ti wọn ba ijakulẹ pade nitori awọn gomina naa ko ri ohunkohun ṣe si ọrọ naa lati bi ọdun meji sẹyin.
Ko ṣai m’ẹnuba ba pe gbogbo ẹya ẹgbẹ OPC, awọn figilante, to fi mọ awọn ọlọdẹ ibilẹ lo ti ṣetan lati pawọpọ lori ati koju iṣoro eto aabo ni ẹkun naa.
Ni pataki, o ṣe alaye pe ọrọ eto aabo kọja ọrọ ohun-ija (weapon) nikan, iṣẹ ọtẹlẹmuyẹ, alami, olobo, ifọwọsowọpọ ara-ilu, agbara ibilẹ ati bẹẹ bẹẹ lọ naa ṣe pataki pupọ lati ja ija iṣẹgun.
“Gbogbo oju la gbọdọ mu to ọrọ kikoju awọn ọdaran yii.”