Igun Turaki Ninu Ẹgbẹ Oṣelu PDP Ni Ko Si Iye Idurunmọ To Le Fa K’awọn Ma Fa Jonathan Kalẹ Bi Igun Wike Ṣe N Gbe Igbesẹ Lati Di Ọna Mọ Wọn

Igun ẹgbẹ oṣelu PDP ti Tanimu Turaki n lewaju fun ni wọn ti sọ pe ko si iye idurunmọ to le fa k’awọn ma fi aarẹ tẹlẹri Goodluck Jonathan lede gẹgẹ bi adije dupo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu naa.

Ti ẹ o ba gbagbe iṣakoso olu-ilu ile wa ni wọn wọgi le ki awọn ile itura, ile igbafẹ ati awọn gbọngan ijọba loriṣiriṣi lati ṣiṣẹ pọ pẹlu awọn alaṣẹ ẹgbẹ oṣelu ti ajọ INEC da mọ nikan.

Nigba ti wọn n fesi, ẹni to jẹ akọwe igun Turaki, Ọgbẹni Ini Ememobong sọ pe awọn ti wọn ni gbọngan ti wọn fẹ lo tẹle sọ pe Minisita fun Olu-ilu ilẹ wa Nyesom Wike d’ẹru ba wọn lati ti gbọngan wọn pa ti wọn ba gba ki wọn lo gbọngan wọn fun ifọwọsi adije dupo aarẹ kankan.

O ṣapejuwe ofin ti Wike gbe kalẹ gẹgẹ bii igbiyanju lati dena awọn ẹgbẹ oṣelu mii ti ko dẹ si ofin to fun minisita naa ni agbara lati sọ pe ki gbọngan ma ṣe nkan to niṣe pẹlu oṣelu.

Ẹwẹ, igun ẹgbẹ oṣelu PDP ti minisita Nyesom Wike n ṣatilẹyin fun ti Abdulraman Mohammed n lewaju fun ti jina si apejọpọ ti igun Tanimu Turaki n gbero lati ṣe lati gbe owo Goodluck Jonathan soke gẹgẹ bii adije dupo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu PDP naa.

Akọwe ẹgbẹ naa Jungudo Mohammed ninu ọrọ kan to fi lede lo ti ṣapejuwe apejọpọ naa gẹgẹ bii irọ ati igbesẹ lati fa gbọnmisi-omi-o-to l’agbọn oṣelu.

O wa pe fun awọn ọmọ ẹgbẹ lati kọti ọgbọin si apejọpọ naa bẹẹ lo n pe Jonathan lati yọ ara rẹ kuro ninu irọ ti wọn n fi wọde yii.

E ṣe ranti pe igun Wike ni wọn fa ọmọ ile-igbimọ aṣofin-agba kalẹ gẹgẹ bii adije dupo ẹgbẹ naa fun idibo ọdun 2027.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search