Mo Bimpe Iyawo Lafeef Ni Aimọye Igba Ni Wọn D’ẹyẹ S’oun Nitori Airọmọbi

Mo Bimpe Iyawo Lafeef Ni Aimọye Igba Ni Wọn D'ẹyẹ S'oun Nitori Airọmọbi

A ṣe lootọ ni pe aye kii fẹ ba aladanwo ṣe. Irawọ oṣere tiata, Bimpe Oyebade t’awọn ololufẹ rẹ mọ si Mo Bimpe to tun jẹ aya fun gbajugbaja oṣere, Lateef Adedimeji lo ti mẹ’nu l’ọrọ l’ori awọn adanwo ti oju rẹ kan l’asiko to n ṣ’awaari, ti o ti ṣabiamọ f’ọkọ rẹ Lateef Adedimeji.

Mo Bimpe lo ṣalaye irobinujẹ alagbara t’oun to la kọja ninu fọnran kan to fi si’ta l’ori atẹ Instagram lẹyin to de lati ibi ayẹyẹ ọjọ-ibi ọdun kan Rakeem to jẹ ọmọ-ọmọ gbajugbaja oṣere, Iyabọ Ojo.

 

Ninu fọnran naa ni Mo Bimpe ti ṣalaye pe o to asiko kan nigba t’oun wo’ju Oluwa fun ọlẹ ayọ t’awọn eeyan bẹrẹ si ni d’ẹyẹ s’oun, ti wọn o si pe oun si’bi ayẹyẹ ọlọmọ kankan nitori p’oun o ti ri bi ni’gba naa.

O ni awọn to d’ẹyẹ s’oun yii jẹ awọn t’awọn ti jọ ṣiṣẹ pọ, r’ẹrin pọ, t’oun si fẹ wọn denudenu. O ni oun o tete fura, oun kan ṣadede ṣakiyesi pe wọn ti yọ oun sẹyin lawujọ ọlọmọ ni.

Oṣerebirin naa ni eyi jẹ ohun to dun ohun gidigidi nitori ibanujẹ air’ọmọ gbe jo gan-an ti to lọtọ, ka to sọ ti ẹkọ ibanujẹ t’awọn aye tun-un fi iwa wọn po f’oun mu.

O ni inu oun to bajẹ kii kuku ṣe nitori k’aye le k’aanu oun ṣugbọn t’oun kan jẹ ẹda to fẹran awọn ọmọ wẹwẹ, t’oun si nifẹẹ lati ma a ba wọn k’ẹyẹ ṣugbọn t’awọn aye o jẹ nitori p’oun n ṣ’awaari.

Mo Bimpe lo pada n sọ ti’nu rẹ ja’de lẹyin ti Ọlọhun ti da l’are pẹlu ibẹta lantilanti. O wa rọ awọn eeyan pe ki wọn ma tun mu aye le koko si f’awọn to ba n sunkun ọmọ, bẹẹ ki wọn o ma yọ wọn kuro ninu ọrẹ, ninu ẹgbẹ abi yọ wọn sẹyin ninu ayẹyẹ. O ni dipo bẹẹ ifẹ lo yẹ ki wọn o ma a fi han si wọn nitori eeyan kan o le sọ gẹlẹ ohun ti wọn la kọja b’oju wọn ti lẹ gun rege.

Lo ba tun kọju si awọn iya ireti t’oun jagun ati bi ti wọn n pe ni ‘TTC Mom’ lati ma sọ ireti nu, o l’oun mọ pe ireti pipẹ a ma ṣ’ọkan l’aarẹ, amọ ṣa, t’oun mọ pe b’ẹkun pẹ titi ayọ n bọ dandan. O ni iru oun t’oun bi’kan tẹlẹ, t’oun si pada di iya ibẹta, o ni k’awọn iya ireti ẹgbẹ oun igba kan gba pe iru ibukun oun le kaari wọn, pe Oluwa t’oun se’bẹ o kuro ni’di aaro.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search