Gomina ipinlẹ Ọyọ, Onimọ ẹrọ Seyi Makinde ti buwọlu aṣẹ ẹlẹẹkeji ti ọdun 2026 lati ṣe ironilagbara fun eto aabo, ṣiṣe ofin to niṣe pẹlu iwe irinna ati imugbooro igbokegbodo ọkọ nipinlẹ Ọyọ.
Aṣẹ naa to buwọlu loni lo fi gbendeke si iṣẹ awọn ọlọkada pẹlu bi ibẹru ṣe wa lọkan ọpọ awọn eeyan lori eto aabo lẹyin ti awọn ẹlẹkẹru agbesunmọmi ṣe ikọlu si awọn ile-iwe mẹta ọtọọtọ nijọba ibilẹ Oriire nipinlẹ Ọyọ.
Nigba to n sọrọ nibi to ti n buwọlu lu aṣẹ naa, Makinde ni awọn ọkọ, ọkada ati kẹkẹ ẹlẹsẹ mẹta ti wọn o ni iwe irinna ni awọn ọdaran n lọ lati ṣiṣẹ laabi leyi to m fa ki awọn ẹṣọ alaabo ma le ri ọwọ to wọn.
O ṣalaye pe aṣẹ yii yoo fi ofin de ṣiṣe iwe irinna ati ofin irinna bẹẹ ni yoo f’aye silẹ fun awọn ajọ tọrọ kan lati fi kele ofin gbe awọn ti wọn ba ru’fin.
O ṣalaye pe aṣẹ yii yoo fi ofin de ṣiṣe iwe irinna ati ofin irinna bẹẹ ni yoo f’aye silẹ fun awọn ajọ tọrọ kan lati fi kele ofin gbe awọn ti wọn ba ru’fin.
Gomina ni ko saaye fun awọn ọlọkada lati ṣiṣẹ laarin aago mẹwa aabọ aṣalẹ si aago marun aabọ aarọ (10:30pm – 5:30am) kaakiri ipinlẹ Ọyọ. O ṣapejuwe igbesẹ naa gẹgẹ bi eyi ti yoo dẹkun iwa ọdaran ti yoo si imugbooro ba aabo araalu.
O tẹsiwaju pe awọn ẹkọ lati ikọlu nipinlẹ Ọyọ paapaa julọ ti ijọba ibilẹ Oriire lo fa ipinnu ijọba lati ṣe afikun ọna a n gba daabobo ilu.
Gomina Makinde wa rọ awọn araalu lati ṣatilẹyin f’awọn ẹṣọ alaabo nipa fifi ẹjọ sun kia ti wọn ba ri nkan to mu ifura dani bẹẹ lo gboṣuba kare f’awọn ẹṣọ alaabo ati awọn ikọ Amọtẹkun fun iṣẹ takuntakun lati daabobo awọn araalu ati dukiya.