Ẹgbọn Ati Olori Ti Mo Bọwọ Fun Ni Atiku, Mi O Le Sa Fun – Peter Obi

Gomina tẹlẹri nipinlẹ Anambra to tun jẹ adije dupo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu NDC, Peter Obi ti fẹnu ṣaata awọn ọrọ to n lọ pe oun n sa fun igbakeji aarẹ tẹlẹri lorilẹede yii Atiku Abubakar ṣaaju idibo ọdun 2027.

Obi lo sọ eyi di mimọ nibi ipade kan to waye l’agbegbe Cape Town lorilẹede South Africa pẹlu bi awuyewuye ṣe n lọ lori bi nkan ṣe ri laarin oun ati Atiku l’agbọn oṣelu lọwọ yii.

O ni ko wọpọ ninu awọn eeyan to sunmọ Atiku b’oun ṣe sunmọ nitori olori t’oun bọwọ fun gidi ati ẹgbọn daadaa lo jẹ s’oun.

O tẹsiwaju pe oun o sa fun-un lailai bẹẹ l’oun o ki n sa f’ẹnikẹni, o kan jẹ pe ilana a n gba ṣe nkan t’oun lo yatọ.

Ọrọ yii jẹ jade lẹyin ọpọlọpọ oṣu t’awọn oloṣelu mejeeji gbiyanju lati fọwọsowọpọ ni igbaradi fun idibo ọdun 2027 pẹlu ẹgbẹ oṣelu ADC.

Atiku ki Obi kaabọ sinu ẹgbẹ oṣelu ADC ni ọjọ kini oṣu kini ọdun yii ni igbaradi fun ifọwọsowọpọ lati yọ Aarẹ Tinubu l’oye l’ọdun 2027 ṣugbọn ifọwọsowọpọ naa ko yọri si rere.

Obi kuro ninu ẹgbẹ oṣelu ADC latari aigbọra ẹni ye laarin awọn ọmọ ẹgbẹ naa leyi to mu ki oun ati Rabiu Kwankwanso lọ darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu NDC fun imugbooro orilẹede Naijiria gẹgẹ bo ṣe wi.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search