Alema t’ilu Warri, Agba Oye Emmanuel Oritsejolomi Uduaghan ti sọ pe ki aya aarẹ orilẹede Naijiria, Remi Tinubu f’oju si iṣẹ ile idana, ko ye da si ọrọ awọn eeyan Itsekiri.
Nigba to n sọrọ nibi ayẹyẹ kan, ori ade naa ni aya aarẹ o ni nkan ṣe pẹlu iṣejọba aarẹ rara. O sọrọ gba Remi Tinubu fun ilọwọsi rẹ ninu ọrọ to ni ṣe pẹlu agbegbe Warri ati ipinlẹ Delta.
Oloye naa beere nkan to kan aya aarẹ lori ọrọ Warri to si n jiyan pe o yẹ ki o ṣamojutọ awọn ọrọ to n ba awọn araalu lọkan jẹ.
Siwaju si, sọrọ lori eto aabo to mẹhe lorilẹ-ede Naijiria bẹẹ lo n bu ẹnu atẹ lu esi ti aya aarẹ fi si ọrọ to n ba inu ọpọlọpọ ẹbi jẹ.
Gẹgẹ bo ti wi, o pe Remi Tinubu o ni aaye ni ọfiisi aarẹ nitori iṣẹ ọwọ rẹ ko yẹ ko kọja itọju ọkọ ati awọn ọmọ rẹ. O ni, kaka ko wa ninu ile idana ko maa tọju ọkọ ati ọmọ, o lọ joko s’Abuja.
Agba Oye naa tẹsiwaju pe wọn ji awọn ọmọ gbe kaakiri orilẹede Naijiria ṣugbọn ko fi aidunnu han gẹgẹ bii abiyamọ.