Awọn ọmọ ibeji Olaide John-Paul to jẹ aburo minisita tẹlẹ fun ọrọ ina-ọba, Adebayọ Adelabu ni awọn ọlọpa ti doola pada l’ọjọ Abamẹta (Satide) l’ẹyin ọjọ mẹta ni akata awọn ajinigbe.
Awọn ibeji naa ni awọn ajinigbe da l’ọna, ti wọn si jigbe l’oju ibọn ni Ọjọru (Wednesday) to kọja ni’lu Ibadan, ipinlẹ Ọyọ.
Agbẹnusọ ile-iṣẹ Ọlọpa ipinlẹ Ọyọ, DSP Oluṣọla Ayanlade fi idi rẹ mu’lẹ pe awọn ọlọpa “ti doola awọn ọmọ naa ni ayọ ati alaafia lai si ifa’rapa kankan.” O tẹsiwaju pe, alaye siwaju si yoo tun tẹle laipẹ.
Ṣaaju ni Arakunrin Fẹmi Awogbọrọ, ọkan ninu awọn agbẹnusọ fun Adelabu fi si’ta pe awọn ibeji ọmọ ọdun mejila (12-year-old twin sons) John-Paul, ti orukọ wọn n jẹ Peter ati Paul, ni wọn ji gbe ni nnkan aago meje aabọ owurọ (around 7:30am) l’oju ọna lọ si ile-ẹkọ wọn ni ilu Ibadan.
Iroyin idoola awọn ọmọ aburo Adelabu lo n wa’ye l’asiko ti awọn akẹẹkọ ati olukọ ni ijọba ibilẹ Oriire ni agbegbe Ogbomoṣọ ni ipinlẹ Ọyọ naa ṣi wa ni akata awọn ajinigbe-agbesunmọmi lati bi ọjọ mejilelogun sẹyin, l’aarin ifẹhonuhan; iṣọrọ-soke ati bẹẹ bẹẹ lọ to ti tẹle iṣẹlẹ ikaaya naa.