Igbimọ Alaṣẹ Igun ẹgbẹ oṣelu PDP ti Gomina ipinlẹ Ọyọ, Onimọ ẹrọ Seyi Makinde n ṣatilẹyin fun ni wọn ti yan igbimọ alabojuto ẹlẹni mẹtala pẹlu Tanimu Turaki (SAN) gẹgẹ bi Alaga. Awọn ti wọn wa ninu igbimọ naa ni, Alhaji Hamza Akuyam Koshe, Dokita Daniel Woyenikuro, Richard Ihediwa, Isa Abubakar, Okechekwu Obiechina Daniel, Theophilus Dakas Shan, Ini Ememobong, Aribisala Adewale Idowu, Bara’u Shafi, Mrs Anthonia Chinenyenwa, Umar Dan Aji, ti igbakeji gomina tẹlẹri ni ipinlẹ Oyo, Amb Taofeek Arapaja si jẹ akọwe.
Ipinnu lati da igbimọ yii silẹ waye lẹyin ipade kẹtalelọgọrun ti igbimọ alaṣẹ ti Igun Seyi Makinde igun ẹgbẹ naa nilu Abuja. Alaga ẹgbẹ oṣelu PDP ni ipinlẹ Edo Tony Aziegbemi lo mu aba naa wa nigbati Clement Fagboyede si gbe lẹyin.
Nigba to n ba awọn akọroyin sọrọ leyin Ipade naa, Makinde ni igun oun o ni dẹyin ninu ijangbara naa.
Ninu esi tiwọn, igun ti Minisita fun Olu-ilu ilẹ wa, Nyesom Wike n ṣatilẹyin fun ti kọ esi ipade igbimọ naa nitori wọn o ni aṣẹ lati yan igbimọ kankan. Wọn tẹsiwaju pe igbimọ amuṣẹya ti wọn yan ko mulẹ labẹ ofin.
Ti ẹ o ba gbagbe, ọgbọn ọjọ oṣu kẹrin ọdun yii ni Ile-ẹjọ to gaju nilẹ wa wọgi le ipejọpọ igun awọn Seyi Makinde to waye nilu Ibadan laarin ọjọ kẹẹdogun si ọjọ kẹrindinlogun oṣu kọkanla Ọdun to kọja eyi to fi Turaki jẹ gẹgẹ bi Alaga.
Nigba ti wọn n fesi si idajọ Ile-ẹjọ, Alaga Igbimọ Alabojuto igun Seyi Makinde, Adolphus Wabara sọ pe ti awọn ba tẹle aṣẹ Ile-ẹjọ, ẹgbẹ oṣelu naa ko ni ni iṣakoso to dantọ atipe awọn ṣe nkan to yẹ gẹgẹ bii iwe ofin ẹgbẹ naa ṣe faaye ẹ silẹ.
Ẹwẹ igun ti Wike ti bẹnu atẹ lu ọrọ naa pe irọ patapata ni nitori Abdulrahman Mohammed ati Anyanwu ṣi wa l’agbọn iṣakoso gẹgẹ bi Alaga ati Akọwe.
Lana ode yii ni igun Seyi Makinde ninu ẹgbẹ oṣelu PDP fi aaye silẹ fun awọn ti wọn ba fẹ dije lati ra fọọmu wọn bẹrẹ lati oni yii nigba ti igun Wike ti bẹrẹ tita lati ọjọ kẹtadinlọgbọn oṣu to kọja.
Ni bayi, ko tii han si gbangba igba ti laasigbo oṣelu ninu ẹgbẹ oṣelu PDP yoo wa s’opin.