Ile-ẹjọ giga to fikalẹ s’ilu Eko ti kede pe owo aadọfa biliọnu (₦110 billion) to n fa ariyanjiyan ti ile aṣofin ilẹ wa na lori ọkọ ati eto owo ajẹmọnu ko ba ofin mu.
Owo aadọfa biliọnu ọhun leyi ti wọn na ogoji biliọnu (₦40 billion) le ọkọ ayọkẹlẹ aarundinlaaadọta le ni irinwo (465) ati aadọrin biliọnu (₦70 billion) le owo ajẹmọnu fun awọn aṣofin ti wọn ṣẹṣẹ yan ni ile-ẹjọ wọgi le pe o kọlu ofin, ohun ti iwe ofin sọ ati ifọkantan awọn araalu.
Ile-ẹjọ naa wa paa l’aṣẹ fun aarẹ ile igbimọ aṣofin, Godswill Akpabio ati abẹnugan ile igbimọ aṣojuṣofin, Tajudeen Abass lati ri pe gbogbo owo ti wọn ba maa na lati isinyi lọ gbọdọ tẹle ilana to tọ ati ofin toto.
Idajọ naa lo tẹle igbẹjọ ti ajọ Socio-Economic Rights and Accountability Project (SERAP) fi wọ ile igbimọ aṣofin ilẹ wa lọ siwaju ile-ẹjọ.
Ninu atẹjade kan ti igbakeji adari ajọ SERAP, Kolawole Oluwadare buwọlu ni ajọ naa ti ni ninu oṣu kẹjọ ọdun 2023 l’awọn mu igbẹjọ tako Akpabio ati Abass lori owo aadọfa biliọnu ti wọn fẹ naa lori ọkọ ati owo ajẹmọnu fun awọn ọmọ ile igbimọ aṣofin tuntun pẹlu bi ilu o ṣe f’ara rọ l’agbọn ọrọ aje.
Nigba to n gbe idajọ rẹ kalẹ, Adajọ Yellim Bogoro ni wọn o tẹle ofin lori awọn nkan ti wọn na owo naa le lori bẹẹ lo jẹ pe awọn tiwọn buwọlu naa ni wọn ni owo naa to si fi han pe apo ara wọn ni wọn n ja fun.
O tẹsiwaju pe nina aduru owo yẹn lasiko ti ọpọ ọmọ orilẹede Naijiria n ke rora pe ko si owo lapo n ṣafihan aini ifẹ ilu l’ọkan.
Adajọ Bogoro fikun pe anfaani ti ile aṣofin ni lati da ṣiṣẹ ko ni ki ile-ẹjọ ma le yẹ wọn lọwọ wo bi wọn ba n gbe awọn igbesẹ to tako ofin orilẹede Naijiria.
Ninu ọrọ tirẹ, igbakeji adari ajọ SERAP, Kolawole Oluwadare ṣapejuwe idajọ naa gẹgẹ bii ijawe olubori fun ṣiṣe owo ilu bo ṣe yẹ ati pe o tun fi han pe ipo ijọba, ipo araalu ni.
Idajọ naa kede pe ọkọ ti ile igbimọ aṣofin ra ati owo ajẹmọnu naa tako ofin a n gba ra nkan nilẹ yii, ilana ihuwasi ati ibura ofin ilẹ wa ti adajọ si paṣẹ pe wọn gbọdọ tẹle awọn ofin yii ati ilana to tọ fun awọn owo ti wọn ba maa na l’ọjọ iwaju.