Tirela Nla Ti Gba Aarin Mandy Kiss Ati Iya-afẹ Rẹ, Funmi Awelewa Kọja

Gbajumọ ori ẹrọ ayelujara ti ọrọ rẹ maa n saba mu awuyewuye lọwọ, Mandy Ayomiposi ti ọpọ eeyan mọ si Mandy Kiss lo ti wọ iya-afẹ rẹ tẹlẹri, gbajugbaja oṣerebinrin Funmi Awelewa lori ẹrọ ayelujara pe o ba oun laye jẹ.

Mandy Kiss lo fi ẹsun kan Funmi nigba to n fesi si ọrọ kan to jade lati itakun ibanidọrẹ Tiktok lori awọn ilumọọka ti wọn ti jọ rẹ tẹlẹri ki wọn to ja bii Funmi Awelewa, Papaya ati Toyin Abraham.

Nigba to n fesi ninu fọnran kan to fi lede lori itakun ibanidọrẹ Instagram rẹ lo ti ni Papaya nikan l’awọn jọ ni aawọ bi o tilẹ jẹ pe oun o mọọmọ ṣẹ ẹ niṣe lo de oun mọ lori ẹrọ ayelujara nigba ti oun ṣe atunpin ọrọ kan to kan lori ẹrọ ayelujara ṣugbọn Funmi ati Toyin ṣe aida fun oun ni.

O pe Funmi ni aṣiṣe to tobi ju t’oun ṣe laye oun to si ni pe niṣe lo ba oun laye jẹ gidi.

Lẹyin ẹsun ti Mandy Kiss fi kan yii, Funmi Awelewa naa ti jade lati sọrọ ẹnu tiẹ naa. Ninu ọrọ kan to fi lede lori itakun ibanidọrẹ Instagram rẹ lo ti ni ko si ẹnikẹni to to lati ba ti eeyan jẹ nitori ile aye kun fun awọn ipenija oriṣiriṣi.

O ni lootọ oun de Mandy kiss mọ lori ẹrọ ayelujara nitori ko gbọran lẹyin ọpọlọpọ ọrọ iṣiti t’oun ti fun. O tẹsiwaju pe oun o gbe fun ọkunrin ri koda n’iṣe l’oun tun fun niṣẹ pẹlu awọn ile-iṣẹ meji ọtọọtọ nitori naa bawo l’oun ṣe ba laye jẹ.

Funmi ni nitori fọnran kan to fi lede l’oun ṣe ja ara oun kuro ninu ọrẹ t’awọn jọ n ṣe. O ni oun o ro aida si rara nitori oun fẹ ire fun nigba gbogbo.

O wa rọ Mandy Kiss lati tu ba l’ọdọ Ọlọhun ati awọn eeyan to ṣẹ ko de gbe igbe-aye rere.

Ni ipari ọrọ ẹ, o ni ki o fi orukọ oun silẹ, ko ye ba oun l’orukọ jẹ kiri.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search