Gbajugbaja olorin takasufe ti orukọ rẹ ma n ṣaba pariwo lawujọ, Portable Ọmọ Ọlalọmi ti s’ọrọ l’ori iṣoro eto aabo ilẹ wa paapaa julọ l’ori iṣẹlẹ ijinigbe to waye laipẹ yii si awọn ile-ẹkọ kan ni ipinlẹ Ọyọ ati iroyin pe ọwọ awọn ara-ilu ilu kọọkan n tẹ awọn afurasi ọdaran lati oke-ọya ni ipinlẹ Eko ati awọn agbegbe miiran.
Ninu fọnran ti Portable fi sita lori ayelujara lo ti n gba awọn ọmọ kaarọ oojire ni’yanju lati ma bi ikanra aita mọ aje lori iṣẹlẹ ijinigbe to waye ni ipinlẹ Ọyọ, pe ki wọn o ma titori iṣẹlẹ naa sọ gbogbo awọn ara apa oke-ọya to n gbe ni ilẹ Yoruba di afurasi ọdaran nitori o ṣeeṣe ki wọn o ma jẹ ọdaran, ki wọn o dẹ ma fi’ya jẹ alaiṣẹ.
Ninu ọrọ rẹ, o pe “ẹyin eeyan mi. Mo n gbọ pe wọn mu awọn afurasi Awusa ati Fulani lori ifursai iwa ọdaran. Ẹ ma jẹ ka fi ọwọ ara wa ṣe ara wa. Ẹ ma jẹ ka fi iya jẹ alaiṣẹ. Inu igbo ni awọn banditi (jankoriko) wa ti wọn jiyan gbe. O ṣeeṣe ko jẹ awọn alaiṣẹ ni wọn mu ni igboro.”
O ṣo siwaju si pe iṣọkan la nilo lasiko yii gẹgẹ bii ọmọ orilẹ-ede Naijiria dipo iyapa lati le koju awọn ajinigbe-agbesunmọmi, nitori ko si ibi ti awọn jankoriko ko ti le wa.
“Fulani, Yoruba ati Igbo, ẹ dakun, ọkan ni wa. Ọrọ ija kọ l’eyi, ẹ jẹ ka pawọpọ doju kọ awọn jankoriko (banditi). Awọn Yoruba kọọkan wa ninu awọn banditi, bẹẹ ni awọn Awusa naa wa, awọn Fulani koda to fi mọ awọn Igbo wa nínu wọn. Ẹ pawọpọ ṣẹgun banditi lo yẹ.”
Iwoye ti Portable fi sita yii lo n wa’ye l’asiko ti nnkan gb’ona girigiri to oju-ọjọ si k’ọrẹ l’ọwọ ni Naijiria paapaa julọ ni ilẹ Yoruba l’ori ọrọ ijinigbe awọn akẹẹkọ ni ipinlẹ Ọyọ ti ọpọlọpọ awọn eniyan l’ori ayelujara, l’aarin ilu, l’agbo amuludun, ninu ijọba, awọn ijọ ẹlẹsin ati bẹẹ bẹẹ lọ ti n sọrọ soke lori ipenija eto aabo nilẹ yii.