Ijọba ipinlẹ Katsina ti fidi iku ẹni to ti figba kan jẹ agbẹnusọ ikọ ọmọ ologun, ọgagun fẹyinti Major General Rabe Abubakar to ku si akata awọn ajinigbe mulẹ ti wọn si n ṣapejuwe iṣẹlẹ naa gẹgẹ bii ọfọ fun gbogbo ipinlẹ naa ati orilẹede Naijiria lapapọ.
Ikede yii lo jẹyọ ninu atẹjade kan ti kọmiṣọna fun eto aabo abẹnu ati ọrọ ilu, Nasir Muazu fi lede f’awọn oniroyin loni.
Ijọba ipinlẹ Katsina ni ọgagun fẹyinti naa gbẹmi mi latari airitọju to to lori ẹjẹ riru ati itọ ṣuga leyi to n baa ja.
Gẹgẹ bi atẹjade naa ṣe wi, ọpọ akitiyan ijọba ati awọn ẹṣọ alaabo lati doola ọgagun naa l’akata awọn ajinigbe lo ja si pabo.
Ninu atẹjade ọhun, gomina Dikko Umaru Radda ṣapejuwe iṣẹlẹ naa gẹgẹ bii asiko ibanujẹ gidi to n ṣafihan pe o ṣe pataki lati gbe igbesẹ ni kiakia lati f’opin si eto aabo to mẹhe.
O ni ijọba ipinlẹ Katsina ni afojusun lati ṣiṣẹ pọ pẹlu awọn ẹṣọ alaabo ki wọn le fi ọwọ ofin gbe awọn ti wọn wuwa laabi naa bẹẹ lo fi awọn araalu lọkan balẹ pe fifopin si igbesunmọmi jẹ iṣejọba oun logun gidi.
Ni ipari atẹjade naa, ijọba ba awọn ẹbi oloogbe naa kẹdun bẹẹ ni wọn si n gba l’adura pe ki Ọlọrun tẹ s’afẹfẹ ire.
Ti ẹ o ba gbagbe, ọgbọn ọjọ oṣu to kọja l’awọn ẹlẹkẹru agbesunmọmi ji ọgagun fẹyinti Rabe ati iyawo rẹ gbe nigba ti wọn n wa mọto gba Katsina kọja.
L’ọsẹ to koja ni awọn ajinigbe naa beere fun idasilẹ awọn ara wọn mẹta ati awọn maalu ti awọn ẹṣọ alaabo gba lasiko ikọlu gẹgẹ bii ohun idasilẹ awọn l’ọkọ l’aya naa.