Obi, Kwankwaso ati Seriakie Dickson ninu ipade apapo ẹgbẹ NDC
Ẹgbẹ oṣelu Nigeria Democratic Congress (NDC) ti fi tikẹti aarẹ fun idibo ọdun 2027 jin fun iwọ guusu lati ṣe ijọba fun saa kan.
Ipinnu yii lo jẹyọ nibi ipade alakọkọ iru rẹ to n lọ lọwọ bayi fun ẹgbẹ oṣelu NDC nigba ti ẹni to n ṣ’oju Ogbaru nile aṣofin, Afam Victor Ogene mu aba naa wa ti awọn ti wọn jẹ aṣoju nibi ipade naa si gba bẹ.
Wọn tun ṣe ipinnu pe lẹyin saa ọlọdun mẹrin kan, tikẹti naa yoo lọ si Ariwa.
Pẹlu ipinnu yii ọna ti wa ṣi silẹ fun gomina tẹlẹri ni ipinlẹ Anambra, Peter Obi ati awọn adije mii ti wọn wa lati ẹkun guusu lati ra tikẹti aarẹ inu ẹgbẹ naa.
Ẹ ṣe iranti pe ẹgbẹ oṣelu NDC ni wọn ti wa ninu awọn ẹgbẹ oṣelu alatako to n lewaju lẹyin ti Peter Obi ati Rabiu Kwankwanso kuro ninu ẹgbẹ oṣelu ADC lati darapọ mọ ẹgbẹ ọhun. Lẹyin ti Peter Obi ati Kwankwanso ti wọnu ẹgbẹ naa, awọn ọmọ ile Aṣoju ṣofin mẹtadinlogun ni wọn ti ya lọ sinu ẹgbẹ naa lat’inu ẹgbẹ oṣelu ADC kan naa.
Ni bayi, idije ẹni ti yoo koju Aarẹ Bola Tinubu ninu idibo to n bọ lọna n le si bi awọn ẹgbẹ oṣelu alatako naa ṣe n gbaradi lati ri pe awọn gba ijọba.