Eto Aabo: Rarara Ati Davido Wọ Ara Wọn Lori Ayelujara
Ariyanjiyan ti bẹ silẹ laarin onkọrin takasufe David Adeleke ti gbogbo eeyan mọ si Davido ati olorin ilẹ Hausa Dauda Kahutu Rarara leyi to ti mu ariwisi oriṣiriṣi jade lori ẹrọ ayelujara.
Ọrọ naa lo bẹrẹ l’ọjọ iṣẹgun lẹyin ti Rarara fi fọnran kan l’ede lori ẹrọ ayelujara rẹ leyi to fi n bu ẹnu atẹ lu Davido lori ọrọ to sọ nipa eto aabo to mẹhe lorilẹde Naijiria.
Ariyanjiyan yii lo niṣe pẹlu ere ti Davido lọ ṣe nibi igbaradi idije bọọlu ife agbaye nibi to ti wọ aṣọ to ni idanimọ orilẹede Naijiria ati orukọ awọn ọmọ ti wọn jigbe n’ipinlẹ Ọyọ.
Ninu fọnran to ṣe ni Rarara ti bu ẹnu atẹ lu awọn ọrọ ti Davido kọ si aṣọ naa pe o n ṣafihan orilẹede Naijiria lọna odi f’awọn orilẹede agbaye.
Gẹgẹ bo ṣe wi, ọrọ eto aabo gba ki eeyan ṣọra kii ṣe pe ko di nkan ti a n fi oṣelu bọ tabi idi ọrọ nigboro. O ni gbigbe ọrọ aabo si gbangba le ba bi awọn eeyan loke okun ṣe n ri orilẹede Naijiria jẹ.
O tẹsiwaju pe nkan ti Davido ṣe ni ọwọ oṣelu ninu nitori o fẹ fi iyẹn ṣatilẹyin fun aburo baba rẹ to n ṣe oṣelu ko lẹ ṣafihan ijọba to wa l’ode gẹgẹ bii eyi ti ko daa to.
Rarara wa rọ awọn agbefọnranjade l’ori ayelujara lati ṣọra lori ọrọ ti wọn ba n gbe jade lori eto aabo.
Nigba to n fesi, Davido ni ki gbogbo awọn ọmọ orilẹede Naijiria ma dakẹ lori eto aabo to mẹhe bẹẹ ni wọn o gbọdọ da awọn ti wọn baa n sọrọ lẹkun.
O ni o ṣe pataki ki eeyan jẹ aṣoju rere fun orilẹede, ki wọn si ye gbe oṣelu lori ootọ bẹẹ lo ni ki wọn bẹru Ọlọrun ninu gbogbo nkan ti wọn ba n ṣe.
Lẹyin bii wakati meji ni Davido kọ ọrọ kan ni Hausa to fi ba Rarara wi pe to ba jẹ ọlọpọlọ ni, oun o ba wa aaye lati ba jiyan ṣugbọn oun ti ri pe ko mọ nkankan ati pe amukun-un mẹkọ ni.
Lẹsẹkẹsẹ ni Rarara naa ti fesi ninu ariwisi Davido ni ede Hausa to si ni ko ṣọra.
Ọrọ yii lo ti mu awuyewuye lọwọ lori ẹrọ ayelujara bi awọn ololufẹ awọn onkọrin mejeeji ṣe n jiyan lori ipo awọn gbajugbaja lori ọrọ to n lọ nilu.