Omoni Oboli Gbe Sinima Tuntun Jade L'awọn Aye Ba N Bu

Oludamọran pataki lori iroyin si gomina ipinlẹ Delta, Ossai Ovie lo ti bu ẹnu atẹ lu gbajugbaja oṣerebinrin, Omoni Oboli fun pe bo ti gbe sinima ti oloogbe Alexx Ekubo wa ninu rẹ jade lẹyin eto isinku rẹ to si n ṣapejuwe igbesẹ naa gẹgẹ bii igbiyanju lati ri owo ni’di ọfọ.

Ninu ọrọ kan to fi lede lori ikanni ibanidọrẹ Facebook rẹ, Ossai fi aidunnu rẹ han lori ipinnu Oboli lati gbe sinima naa jade lori YouTube lasiko yii, to si n jiyan pe akoko to fi sinima naa sita ko daa to pẹlu pe o fẹ ko owo to ba ri nidi rẹ fun awọn mọlẹbi Alexx.

Gẹgẹ bo ṣe wi, alaye ti o ṣe pe sinima naa sami ibẹrẹ ọrẹ awọn mejeeji ko to lati da gbigbe sinima naa jade lasiko yii lare.

Oludamọran pataki naa ni ileri to ṣe lati ko owo to ba ri nibẹ fun awọn ẹbi oloogbe naa ko yọ pe niṣe lo fẹ fi pa owo si apo ara rẹ kuro.

O ni ọfọ kii ṣe nkan ta fi n gbe fọnran jade lori ẹrọ ayelujara bẹẹ ni isinku kii ṣe ohun to yẹ lati fi ṣe ikede. O fikun pe to ba jẹ pe o fẹ fi buyi fun oloogbe naa lootọ, o yẹ ko fi sinima naa silẹ di igba mii.

Omoni Oboli lo kede gbigbe sinima ti oun ati Alexx jọ ṣe jade lẹyin eto isinku rẹ leyi to ni o sami ibẹrẹ ọrẹ awọn ni bii ọdun mọkanla si mejila sẹyin.

O ni gbogbo owo ti oun ba ri nibẹ l’oun maa ko fun awọn ẹbi rẹ. O wa bẹ awọn ololufẹ lati lọ wo nitori eleyi l’oun fẹ fi gboriyin fun nitori o fi gbogbo ọkan rẹ si sinima naa.

Ti ẹ o ba gbagbe, Alexx Ekubo lo fi aye silẹ ni ẹni ogoji ti wọn si sin ni ilu rẹ, Ujari ni ijọba ibilẹ Arochukwu ni ipinlẹ Abia. Ọpọ awọn ilumọọka, alabaṣiṣẹpọ ati awọn ẹbi ni wọn wa nibi isinku naa.