Wọn Ti S’ọrọ L’aafin Ọọni, Wọn L’awọn O Mọ Ni’pa Oye Ti Baba Ijẹṣa Ni Ọọni F’oun Jẹ

Wọn Ti S'ọrọ L'aafin Ọọni, Wọn L'awọn O Mọ Ni'pa Oye Ti Baba Ijẹṣa Ni Ọọni F'oun Jẹ

Ọrọ ti ja’de lati aafin Ọọni Ile-Ifẹ pe awọn ko mọ nnkan-kan ni’pa pe Ọọni fi oye da gbajugbaja oṣere, Olarenwaju Omiyinka ti ọpọ mọ si Baba Ijẹṣa l’ọla.

Gẹgẹ bii ọrọ ti Moses Ọlafare to jẹ agbenuso kabiesi Ọọni fi si’ta, o ni lootọ ni kabiesi fi ọkọ ta Baba Ijẹṣa l’ọọrẹ ṣugbọn ti oun ko mọ ohunkohun ni’pa ọrọ oye kankan fun Baba Ijẹṣa.

Ọrọ Ọlafare yii to jẹ agbẹnusọ kabiesi lo dabi esi ọrọ si ọrọ kan ti Baba Ijẹṣa kede l’ori ayelujara pe kabiesi Ọọni Ile-Ifẹ, Ọba Adeyẹye Ogunwusi lo da ohun lọla fun ti ọmọkunrin tuntun ti Oluwa fi ta oun l’ọrẹ laipẹ yii. Baba Ijẹṣa ni oniruuru ẹbun l’ọba l’ọba lo n ri gba, ninu eyi ti ẹbun ọkọ ati oye wa ninu rẹ. Baba Ijẹṣa ni oye “Baba Awada Kongẹ Oduwa, Ile-ifẹ, Ile Oodua” ni oun jẹ.

Amọṣa Ọlafare ni ọpọlọpọ ni awọn to ti tẹ’wọ gba ẹbun ọkọ l’ọwọ Ọba Ogunwusi, awọn ọba, awọn ti kii ṣe ọba, awọn amuludun bii Musiliu Haruna Iṣọla, Ṣẹfiu Alao, ti fi mọ oun Ọlafare gan-an fun’ra rẹ ṣugbọn ti ohun ko mọ si ọrọ oye kankan fun Baba Ijẹṣa.

Ẹwẹ, ẹlomiran naa ninu aafin Ọọni to s’ọrọ f’oniroyin lai darukọ ni ọrọ oye jijẹ ko tiẹ ri bẹẹ rara nitori wọn kii deede fi’ni jẹ oye bẹ yẹn.

 

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search