Ojuaye Lasan Lo Kun Tiata, Ko Si’fẹ – Jaiye Kuti

Ojuaye Lasan Lo Kun Tiata, Ko Si'fẹ - Jaiye Kuti

Ilumọọka oṣerebinrin, Jaiye Kuti ti fi aidunnu rẹ han lori bi ko ṣe si irẹpọ ati atilẹyin to peye l’agbo awọn oni tiata, to si ni ọpọ wọn ni wọn maa n fi ipenija wọn pamọ s’abẹ aṣọ.

Nigba to n sọrọ lori eto kan ti wọn pe si, oṣerebinrin naa ni ibaṣepọ laarin awọn oni fiimu ti n dinku nitori gbogbo wọn ni wọn jọ n k’oju ipenija ṣugbọn onikaluku n fi pamọ.

O tẹsiwaju lati sọrọ lori bi owo ṣe maa n jẹ ipenija gidi fun awọn oni sinima, bẹẹ lo ni ọpọ awọn eeyan ni ko ye pe o maa n pẹ ki awọn agbe sinima jade to ri owo wọn pada.

Jaiye Kuti wa sọrọ lori bi awọn eeyan ṣe maa n wo awọn gbajugbaja. O ni bi wọn ṣe ri lori aworan kọ ni wọn ri loju aye rara.

Nigba to n sọrọ lori ohun ti oju rẹ ri, o ni nigba t’oun jade wa sọrọ lori bi wọn ṣe yọ fiimu oun kuro ni awọn sinima kaakiri, ko si ẹnìkankan ninu awọn alabaṣiṣẹpọ oun ti wọn jade ṣatilẹyin fun oun, bi o ti lẹ jẹ pe, gbogbo wọn naa ti k’oju ipenija naa.

O wa ṣe afiwe ọrọ pe, to ba jẹ ọjọ ibi ni, ọpọ wọn ni wọn maa ti ki oun bẹẹ lo ni nitori naa l’oun o ṣe ki ẹnikẹni fun ọjọ ibi mọ, ki awọn naa ma baa ki oun.

Jaiye Kuti ni wọn yọ fiimu rẹ to gbe lọ sinima ni ọjọ kejilelogun oṣu karun-un nitori ariyanjiyan lori asiko ati pinpin pẹlu pe o ni awọn ọpọlọpọ oṣere ninu.

Jaiye jẹ ọkan lara awọn oṣerebinrin to ti ṣe daadaa lẹka fiimu agbelewo ti yoruba ati gẹẹsi. O bẹrẹ iṣẹ tiata ni ọdun 2001 pẹlu ere kan l’ede gẹẹsi ko to di pe o wọ inu ẹka tiata yoruba.

 

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search