Ijọba Apapọ F’ọrọ Ranṣẹ Si South Africa Lori Awọn Ti Wọn Pa Ninu Ikọlu Ikorira Ajeji

Ijọba Apapọ F'ọrọ Ranṣẹ Si South Africa Lori Awọn Ti Wọn Pa Ninu Ikọlu Ikorira Ajeji

Ijọba apapọ ti bu ẹnu atẹ lu bi wọn ṣe pa awọn ọmọ orilẹ-ede Naijiria meji l’orilẹ-ede South Africa, ti wọn si n pe fun iwadi ọrikiniwin ati ijẹjọ awọn ti wọn ṣiṣẹ laabi naa.

Ibẹnu atẹ lu yii lo wa ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ fun ile-iṣẹ ijọba lori ọrọ okere, Kimiebi Ebienfa fi lede.

Gẹgẹ bi ile-iṣẹ ijọba naa ṣe sọ, ọkan lara awọn ti wọn padanu ẹmi wọn ni wọn ni awọn ọlọpa Tshwane Metro Police ṣe’ku pa ni agbegbe Sunnyside, nilu Pretoria nigba ti wọn n gba ọna buburu ṣe ifọrọwanilẹnuwo l’ọjọ kejidinlọgbọn oṣu to kọja.

Wọn ni awọn ọlọpa yi kan naa ni wọn pa ọmọ orilẹ-ede Naijiria kan, Nnaemeka Mathew Andrew Ekpenyong nipakupa ni ogunjọ oṣu kẹrin ọdun yii, ti wọn si fi kun pe, ko tii si ẹnikẹni ti ofin ti gbe lori ọran naa pẹlu pe awọn ọlọpa South Africa mọ awọn tiwọn ṣiṣẹ laabi naa.

Ile-iṣẹ naa ni eleyi n ṣe afihan bi awọn ẹni ibi kan ṣe n gbiyanju lati fi awọn ọmọ orilẹ-ede Naijiria ti wọn n ṣiṣẹ takuntakun pe ọdaran.

Wọn ni orilẹ-ede Naijiria maa n ṣe daadaa pẹlu awọn ọmọ orilẹ-ede mii bẹẹ ni wọn maa n tẹle ofin ni gbogbo igba, nitori naa, ko daa to lati maa f’oju awọn ajoji ra’re nitori bi ilu ṣe ri.

Atẹjade naa kan mi’nu si ọrọ ti agbẹnusọ ijọba sọ lori ẹrọ amohunmaworan pe, ki awọn ọmọ orilẹ-ede Naijiria ti wọn n fi orilẹ-ede South Africa silẹ latari ikorira ajeji lati juwe ibi ti wọn fi awọn ogun oloro pamọ si. Wọn fi kun pe iru ọrọ bẹẹ ko yẹ l’ẹnu ẹni to wa nijọba.

Ijọba apapọ wa pe fun iwadi ni kiakia lori gbogbo awọn ọmọ orilẹ-ede Naijiria ti wọn ti gb’ẹmi lẹnu wọn latari ikorira ajeji ati ijẹjọ awọn ti wọn ṣiṣẹ laabi ọhun.

Wọn wa ba awọn ẹbi awọn oloogbe naa kẹdun awọn ẹni wọn to ba iṣẹlẹ naa lọ, bẹẹ ni wọn rọ awọn ọmọ orilẹ-ede Naijiria lati ma bẹru, ki wọn tẹle ofin bẹẹ ni wọn ni ki wọn maa ṣọra paapaa julọ latari rogbodiyan to n ṣẹlẹ. Wọn fi kun pe ki wọn gbiyanju lati bọ si awọn adugbo ti aabo ba wa.

Ijọba apapọ wa ran ijọba orilẹ-ede South Africa leti pe awọn ọmọ ilu wọn n ṣiṣẹ l’orilẹ-ede Naijiria lai si idiwọ fun idi eyi, ki wọn daabobo awọn ọmọ orilẹ-ede Naijiria ti wọn wa l’akata wọn fun iṣọkan gẹgẹ bii alawọ dudu kan naa.

Leave a Comment

Your email address will not be published.

Start typing and press Enter to search