Oṣerebinrin Etinosa Idemudia, lo ti sọrọ lori ero rẹ nipa oriire, idagbasoke ati ohun ti yoo kọ ọmọ rẹ obinrin to ba bi, lori ifọrọwanilẹnuwo kan.
Gẹgẹ bo ṣe wi, igbeyawo ati ọmọ bibi kii ṣe ọna lati gba wo aṣeyọri eeyan. O ni aṣeyọri kii ṣe lori bi eeyan ba ṣe tẹpa mọ iṣẹ si, bi kii ṣe oore-ọfẹ ati asiko Ọlọrun.
Nigba to n sọrọ lori ẹkọ ti yoo fi le ọmọ rẹ obinrin lọwọ, o ni, oun gbọdọ kọ bi yoo ṣe fun ara rẹ ni ọwọ ati iyi to peye nitori obinrin to ba ni mejeeji, ko si ẹnikẹni to maa f’oju rẹ r’are.
O tẹsiwaju pe, ọpọ igba ni awọn eeyan maa n da awọn obinrin l’ẹjọ ju ọkunrin lọ. O ni fun apẹrẹ, bi obinrin ba ṣe aṣeyọri, awọn eeyan a pe ni aṣẹwo l’awujọ bi o ti lẹ jẹ pe awọn ọkunrin kan naa n ba awọn eeyan sun lati ri nkan ti wọn n wa.
Oṣerebinrin naa wa rọ awọn obinrin lati ma j’owu ara wọn. O ni di po owu, ki wọn maa kọ ẹkọ lara awọn obinrin ẹgbẹ wọn ni.
Etinosa lo fi imọ ẹrọ kọnputa silẹ lati lọ di oṣere tiata ni ọdun 2016to si gbajumọ fun awọn fọnran apanilerin to maa n gbe jade lori itakun Instagram rẹ.